Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 0:52

[1] Ó ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́;

[2] Olúwa fẹ́ràn ẹnu-ọ̀nà Sioni ju gbogbo ibùgbé Jakọbu lọ.

[3] Ohun ológo ni a sọ nípa rẹ̀, ìlú Ọlọ́run,

[4] “Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeli láàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi: Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi, yóò sọ pé, ‘Èyí ni a bí ní Sioni.’ ”

[5] Nítòótọ́, ti Sioni ni a ó sọ, “Eléyìí àti eléyìí ni a bí nínú rẹ̀, àti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ni yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀.”

[6] Olúwa yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀: “Eléyìí ni a bí ní Sioni.”

[7] Àti àwọn olórin àti àwọn tí ń lu ohun èlò orin yóò wí pé, “Gbogbo orísun mi ń bẹ nínú rẹ.”

Ìwé Saamu — Chapters