Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 4:17

[1] Gbà mí, Ọlọ́run, nítorí omi ti kún dé ọrùn mi.

[2] Mo ń rì nínú irà jíjìn, níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé. Mo ti wá sínú omi jíjìn; ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀.

[3] Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́; ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú, nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi.

[4] Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí wọ́n ju irun orí mi lọ, púpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí, àwọn tí ń wá láti pa mí run. A fi ipá mú mi láti san ohun tí èmi kò jí.

[5] Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run; ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú rẹ.

[6] Má ṣe dójútì àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ nítorí mi, Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun; má ṣe jẹ́ kí àwọn tó ń wá ọ dààmú nítorí mi, Ọlọ́run Israẹli.

[7] Nítorí rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn, ìtìjú sì bo ojú mi.

[8] Mo jẹ́ àjèjì si àwọn arákùnrin mi; àlejò sí àwọn arákùnrin ìyá mi;

[9] nítorí ìtara ilé rẹ jẹ mí run, àti ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mí.

[10] Nígbà tí mo sọkún tí mo sì ń fi àwẹ̀ jẹ ara mi ní ìyà èyí náà sì dín ẹ̀gàn mi kù;

[11] nígbà tí mo wọ aṣọ àkísà, àwọn ènìyàn ń pa òwe mọ́ mi.

[12] Àwọn tí ó jókòó ní ẹnu ibodè ń bú mi, mo sì di orin àwọn ọ̀mùtí.

[13] Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni ìwọ ni èmi ń gbàdúrà mi sí Olúwa, ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi rẹ, dá mi lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà rẹ tí ó dájú.

[14] Gbà mí kúrò nínú ẹrẹ̀, má ṣe jẹ́ kí n rì; gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi, kúrò nínú ibú omi.

[15] Má ṣe jẹ́ kí ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni má ṣe jẹ́ kí ọ̀gbìn gbé mi mì kí o má sì ṣe jẹ́ kí ihò pa ẹnu rẹ̀ dé mọ́ mi.

[16] Dá mí lóhùn, Olúwa, nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ; nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ yípadà sí mi.

[17] Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ: yára dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú.

[18] Súnmọ́ tòsí kí o sì gbà mí là; rà mí padà nítorí àwọn ọ̀tá mi.

[19] Ìwọ ti mọ ẹ̀gàn mi, ìtìjú mi àti àìlọ́lá; gbogbo àwọn ọ̀tá mi wà níwájú rẹ.

[20] Ẹ̀gàn ba ọkàn mi jẹ́, wọ́n fi mí sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́; mo ń wá aláàánú, ṣùgbọ́n kò sí, mo ń wá olùtùnú, ṣùgbọ́n n kò rí ẹnìkankan.

[21] Wọ́n fi òróró fún mi pẹ̀lú ohun jíjẹ mi, àti ní òùngbẹ mi, wọ́n fi ọtí kíkan fún mi.

[22] Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó di ìkẹ́kùn ní iwájú wọn, kí ó sì di okùn dídẹ fún àwọn tó wà ní àlàáfíà.

[23] Kí ojú wọn kì í ó ṣókùnkùn, kí wọn má ṣe ríran, kí ẹ̀yin wọn di títẹ̀ títí láé.

[24] Tú ìbínú rẹ jáde sí wọn; kí ìbínú gbígbóná rẹ bò wọ́n mọ́lẹ̀.

[25] Kí ibùjókòó wọn di ahoro; kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé nínú wọn.

[26] Nítorí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ẹni tí ìwọ ti lù, àti ìrora àwọn tí ó ti ṣèṣe.

[27] Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn; Má ṣe jẹ́ kí wọn pín nínú ìgbàlà rẹ.

[28] Jẹ́ kí a yọ wọ́n kúrò nínú ìwé ìyè kí á má kà wọ́n pẹ̀lú àwọn olódodo.

[29] Ṣùgbọ́n tálákà àti ẹni-ìkáàánú ni èmí, Ọlọ́run, jẹ́ kí ìgbàlà rẹ gbé mi lékè.

[30] Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run ga èmi yóò fi ọpẹ́ gbé orúkọ rẹ̀ ga.

[31] Eléyìí tẹ́ Olúwa lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọ ju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo rẹ̀ àti bàtà rẹ̀.

[32] Àwọn òtòṣì yóò rí, wọn yóò sì yọ̀: ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yín yóò sì wà láààyè!

[33] Olúwa, gbọ́ ti aláìní, kì ó sì kọ àwọn ìgbèkùn sílẹ̀.

[34] Kí ọ̀run àti ayé yìn ín, òkun àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀,

[35] nítorí tí Ọlọ́run yóò gba Sioni là yóò sì tún àwọn ìlú Juda wọ̀nyí kọ́. Kí wọn ó lè máa gbé ibẹ̀, kí wọn ó lè máa ní ní ilẹ̀ ìní;

[36] àwọn ọmọ ọmọ ọ̀dọ̀ ni yóò máa jogún rẹ̀, àwọn tí ó fẹ́ orúkọ rẹ ni yóò máa gbé inú rẹ̀.

Ìwé Saamu — Chapters