Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 1:54

[1] Gbọ́, Olúwa, kí o sì dá mi lóhùn, nítorí mo jẹ́ tálákà àti aláìní.

[2] Dáàbò bò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ: ìwọ ni Ọlọ́run mi, gbà ìránṣẹ́ rẹ là tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.

[3] Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń pè ọ́ ní gbogbo ọjọ́.

[4] Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ rẹ, nítorí ìwọ, Olúwa, ni mo gbé ọkàn mí sókè sí.

[5] Ìwọ ń dáríjì, ìwọ sì dára, Olúwa, ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́.

[6] Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa; tẹ́tí sí ẹkún mi fún àánú.

[7] Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi èmi yóò pè ọ́, nítorí ìwọ yóò dá mi lóhùn.

[8] Nínú àwọn òrìṣà kò sí ẹni tí ó dàbí i rẹ, Olúwa: kò sí àwọn iṣẹ́ tí a lè fiwé tìrẹ.

[9] Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ dá yóò wá láti wá jọ́sìn níwájú rẹ, Olúwa; wọn ó mú ògo wà fún orúkọ rẹ̀.

[10] Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ sì ń ṣe ohun ìyanu; ìwọ nìkan ni Ọlọ́run.

[11] Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa, èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ; fún mi ní ọkàn tí kì í yapa, kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ.

[12] Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi; èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé.

[13] Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi; ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú.

[14] Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run; àti ìjọ àwọn alágbára ń wá ọkàn mi kiri, wọn kò sì fi ọ́ pè.

[15] Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere, Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.

[16] Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi; fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là.

[17] Fi àmì hàn mí fún rere, kí àwọn tí ó kórìíra mi lè ri, kí ojú lè tì wọ́n, nítorí ìwọ Olúwa ni ó ti tù mí nínú.

Ìwé Saamu — Chapters