[1] Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, ẹ fi fún Olúwa, ògo àti alágbára.
[2] Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ rẹ̀; sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.
[3] Ohùn Olúwa n ré àwọn omi kọjá; Ọlọ́run ògo sán àrá, Olúwa san ara.
[4] Ohùn Olúwa ní agbára; ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.
[5] Ohùn Olúwa fa igi kedari; Olúwa náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya.
[6] Ó mú Lebanoni fo bí i ọmọ màlúù, àti Sirioni bí ọmọ àgbáǹréré.
[7] Ohùn Olúwa ń ya bí ọwọ́ iná mọ̀nà.
[8] Ohùn Olúwa ń mi aginjù. Olúwa mi aginjù Kadeṣi.
[9] Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀nrín bí, ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòhò. Àti nínú tẹmpili rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé, “Ògo!”
[10] Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi; Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.
[11] Kí Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀; bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.