Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 1:46

[1] Ìwọ ti kọ̀ wá sílẹ̀, Ọlọ́run, ìwọ ti tú wa ká, ìwọ ti bínú nísinsin yìí, tún ara rẹ yípadà sí wa.

[2] Ìwọ ti mú ilẹ̀ wárìrì, ìwọ ti fọ́ ọ; mú fífọ́ rẹ̀ bọ̀ sípò, nítorí tí ó mì.

[3] Ìwọ ti fi ìgbà ewu han àwọn ènìyàn rẹ; ìwọ fún wa ní wáìnì tí ó máa ń ta wá gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.

[4] Àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, ní ìwọ fi ọ̀págun fún kí a lè fihàn nítorí òtítọ́. Sela.

[5] Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbà wá, kí o sì ràn wá lọ́wọ́, kí a lè gba àwọn tí o fẹ́ là.

[6] Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀: “Ní ayọ̀, èmi ó pọ Ṣekemu jáde èmi ó sì wọ́n àfonífojì Sukkoti.

[7] Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase; Efraimu ni àṣíborí mi, Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.

[8] Moabu ní ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi, lórí Edomu ní mo bọ́ bàtà mi sí; lórí Filistia ni mo kígbe ayọ̀.”

[9] Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi nì? Ta ni yóò tọ́ mí lọ sí Edomu?

[10] Kì í ha ń ṣe ìwọ, Ọlọ́run, tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀ tí o kò sì bá ogun wa jáde mọ́?

[11] Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀tá, nítorí asán ni ìrànlọ́wọ́ ènìyàn.

[12] Nípa Ọlọ́run ni a óò ní ìṣẹ́gun, yóò sì tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

Ìwé Saamu — Chapters