[1] Mo fẹ́ ọ, Olúwa, agbára mi.
[2] Olúwa ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi. Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.
[3] Mo ké pe Olúwa, ẹni tí ìyìn yẹ fún, a ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi.
[4] Ìrora ikú yí mi kà, àti ìṣàn omi àwọn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.
[5] Okùn isà òkú yí mi ká, ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí.
[6] Nínú ìpọ́njú mo ké pe Olúwa; mo sọkún sí Olúwa mi fún ìrànlọ́wọ́. Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi; ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀.
[7] Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì, ìpìlẹ̀ àwọn òkè gíga sì ṣídìí; wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú.
[8] Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá; iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá, ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀.
[9] Ó pín àwọn ọ̀run, Ó sì jáde wá; àwọsánmọ̀ dúdú sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
[10] Ó gun orí kérúbù, ó sì fò; ó ń rábàbà lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.
[11] Ó fi òkùnkùn ṣe ibojì rẹ̀, ó fi ṣe ìbòrí yí ara rẹ̀ ká kurukuru òjò dúdú ní ojú ọ̀run.
[12] Nípa ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀, àwọsánmọ̀ ṣíṣú dudu rẹ kọjá lọ pẹ̀lú yìnyín àti ẹ̀yín iná
[13] Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá; Ọ̀gá-ògo sì fọ ohun rẹ̀; yìnyín àti ẹ̀yin iná.
[14] Ó ta àwọn ọfà rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀tá náà ká, ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú.
[15] A sì fi ìsàlẹ̀ àwọn òkun hàn, a sì rí àwọn ìpìlẹ̀ ayé nípa ìbáwí rẹ, Olúwa, nípa fífún èémí ihò imú rẹ.
[16] Ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi gíga, ó sì dì mímú; Ó fà mí jáde láti inú omi jíjìn.
[17] Ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára, láti ọwọ́ àwọn ọ̀tá, ti ó lágbára jù fún mi.
[18] Wọ́n dojúkọ mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi; ṣùgbọ́n Olúwa ni alátìlẹ́yìn mi.
[19] Ó mú mi jáde wá sínú ibi ńlá; Ó gbà mí nítorí tí ó ní inú dídùn sí mi.
[20] Olúwa ti hùwà sí mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi, ó ti fi èrè fún mi.
[21] Nítorí mo ti pa ọ̀nà Olúwa mọ́; èmi kò ṣe búburú nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.
[22] Gbogbo òfin rẹ̀ ni ó wà níwájú mi; èmi kò sì yípadà kúrò nínú ìlànà rẹ̀.
[23] Mo ti jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú rẹ̀; mo sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.
[24] Olúwa san ẹ̀san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi níwájú rẹ̀.
[25] Fún olóòtítọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní olóòtítọ́, sí aláìlẹ́bi, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi,
[26] sí ọlọ́kàn mímọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní ọlọ́kàn mímọ́, ṣùgbọ́n sí ọlọ́kàn-wíwọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní òǹrorò.
[27] O pa onírẹ̀lẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ó rẹ àwọn ti ń gbéraga sílẹ̀.
[28] Ìwọ, Olúwa, jẹ́ kí fìtílà mi kí ó máa tàn; Ọlọ́run mi, yí òkùnkùn mi padà sí ìmọ́lẹ̀.
[29] Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, èmi sáré tọ ogun lọ; pẹ̀lú Ọlọ́run mi mo lè fo odi kan.
[30] Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà rẹ̀ pé, a ti rídìí ọ̀rọ̀ Olúwa òun ni àpáta ààbò fún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.
[31] Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe Olúwa? Ta ní àpáta bí kò ṣe Olúwa wa?
[32] Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrè ó sì mú ọ̀nà mi pé.
[33] Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín; ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga.
[34] Ó kọ́ ọwọ́ mi ni ogun jíjà; apá mi lè tẹ ọrùn idẹ.
[35] Ìwọ fi asà ìṣẹ́gun rẹ̀ fún mi, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé mí dúró; àti ìwà pẹ̀lẹ́ rẹ̀ sọ mí di ńlá.
[36] Ìwọ sọ ìrìn ẹsẹ̀ mi di ńlá ní ìsàlẹ̀ mi, kí kókó-ẹsẹ̀ mi má ṣe yẹ̀.
[37] Èmi lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì bá wọn èmi kò sì padà lẹ́yìn wọn títí a fi run wọ́n.
[38] Èmi sá wọn ní ọgbẹ́ tí wọn ko fi le è dìde; wọ́n ṣubú ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
[39] Nítorí ìwọ fi agbára dì mí ní àmùrè fún ogun náà; ìwọ ti mú àwọn tí ó dìde si mí tẹríba ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
[40] Ìwọ yí ẹ̀yìn àwọn ọ̀tá mí padà sí mi èmi sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.
[41] Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbà wọ́n, àní sí Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn.
[42] Mo lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí eruku níwájú afẹ́fẹ́; mo dà wọ́n síta gẹ́gẹ́ bí ẹrọ̀fọ̀.
[43] Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn; Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí,
[44] ni wéré ti wọ́n gbọ́ ohùn mi, wọ́n pa àṣẹ mi mọ́; àwọn ọmọ àjèjì yóò tẹríba fún mi.
[45] Àyà yóò pá àlejò; wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù jáde láti ibi kọ́lọ́fín wọn.
[46] Olúwa wà láààyè! Olùbùkún ni àpáta mi! Gbígbéga ní Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
[47] Òun ni Ọlọ́run tí ó ń gbẹ̀san mi, tí ó sì ń ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní abẹ́ mi,
[48] tí ó pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mí. Ìwọ gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí mi lọ; lọ́wọ́ àwọn ènìyàn alágbára ni ìwọ ti gbà mí.
[49] Títí láéláé, èmi yóò máa yìn ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ Olúwa; èmi yóò sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.
[50] Ó fún ọba rẹ̀ ni ìṣẹ́gun ńlá; ó fi ìkáàánú àìṣẹ̀tàn fún ẹni àmì òróró rẹ̀, fún Dafidi àti ìran rẹ̀ títí láé.