Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 1:38

[1] Olúwa gbọ́ àdúrà mi, fetísí igbe mi fún àánú; nínú òtítọ́ àti òdodo rẹ, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi.

[2] Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìdájọ́, nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè tí ó ṣe òdodo níwájú rẹ.

[3] Ọ̀tá ń lépa mi, ó fún mi pamọ́ ilẹ̀; ó mú mi gbé nínú òkùnkùn bí àwọn tí ó ti kú ti pẹ́.

[4] Nítorí náà ẹ̀mí mi ṣe rẹ̀wẹ̀sì nínú mi; ọkàn mi nínú mi ṣì pòruurù.

[5] Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́; èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ mo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ rẹ ti ṣe.

[6] Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ: òǹgbẹ rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. Sela.

[7] Dá mi lóhùn kánkán, Olúwa; ó rẹ ẹ̀mí mi tán. Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára mi kí èmi má ba à dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò.

[8] Mú mi gbọ́ ìṣeun ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀: nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé. Fi ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí, nítorí èmi gbé ọkàn mi sókè sí ọ.

[9] Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Olúwa, nítorí èmi fi ara mi pamọ́ sínú rẹ.

[10] Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ rẹ, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ dídára darí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.

[11] Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa, sọ mi di ààyè; nínú òdodo rẹ, mú ọkàn mi jáde nínú wàhálà.

[12] Nínú ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà, ké àwọn ọ̀tá mi kúrò, run gbogbo àwọn tí ń ni ọkàn mi lára, nítorí pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ.

Ìwé Saamu — Chapters