[1] Olúwa, gbà mi lọ́wọ́ ọkùnrin búburú u nì, yọ mí lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì,
[2] ẹni tí ń ro ìwà búburú ní inú wọn; nígbà gbogbo ni wọ́n ń rú ìjà sókè sí mi.
[3] Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò, oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ ní abẹ́ ètè wọn.
[4] Olúwa, pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú; yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì ẹni tí ó ti pinnu rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú.
[5] Àwọn agbéraga ti dẹkùn sílẹ̀ fún mi àti okùn: wọ́n ti na àwọ̀n lẹ́bàá ọ̀nà; wọ́n ti kẹ́kùn sílẹ̀ fún mi.
[6] Èmi wí fún Olúwa pé ìwọ ni Ọlọ́run mi; Olúwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
[7] Olúwa Olódùmarè, agbára ìgbàlà mi, ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà.
[8] Olúwa, máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún un; má ṣe kún ọgbọ́n búburú rẹ̀ lọ́wọ́; kí wọn kí ó máa ba à gbé ara wọn ga. Sela.
[9] Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi káàkiri ni, jẹ́ kí ète ìka ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀.
[10] A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára, Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná, sínú ọ̀gbun omi jíjìn, kí wọn kí ó má ba à le dìde mọ́.
[11] Má ṣe jẹ́ kí aláhọ́n búburú fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ní ayé; ibi ni yóò máa dọdẹ ọkùnrin ìkà nì láti bì í ṣubú.
[12] Èmi mọ̀ pé, Olúwa yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró, yóò sì ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tálákà.
[13] Nítòótọ́ àwọn olódodo yóò máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ; àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yóò máa gbé iwájú rẹ.