Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 0:49

[1] “Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa,” kí ni Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;

[2] ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa, nígbà tí àwọn ènìyàn gbógun sí wa,

[3] nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa,

[4] nígbà náà ni omi wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀,

[5] nígbà náà ni agbéraga omi ìbá borí ọkàn wa.

[6] Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n bí ohun ọdẹ fún eyín wọn.

[7] Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ; okùn já àwa sì yọ.

[8] Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa, tí ó dá ọ̀run òun ayé.

Ìwé Saamu — Chapters