Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 1:54

[1] Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́; má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ẹ́.

[2] Wo bí àwọn ọ̀tá rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ, bi àwọn ọ̀tá rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè.

[3] Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ; wọn sí dìtẹ̀ mọ́ àwọn tí o fẹ́.

[4] Wọn wí pé, “wá, ẹ jẹ́ kí á pa wọ́n run bí orílẹ̀-èdè, kí orúkọ Israẹli ma bá a sí ní ìrántí mọ́.”

[5] Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan; wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ

[6] Àgọ́ Edomu àti ti àwọn ará Iṣmaeli, ti Moabu àti ti Hagari

[7] Gebali, Ammoni àti Amaleki, Filistia, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Tire.

[8] Asiria pẹ̀lú ti darapọ̀ mọ́ wọn láti ran àwọn ọmọ Lọti lọ́wọ́. Sela.

[9] Ṣe sí wọn bí ìwọ ti ṣe sí Midiani bí o ti ṣe sí Sisera àti Jabini ní odò Kiṣoni,

[10] ẹni tí ó ṣègbé ní Endori tí wọn sì dàbí ààtàn ní orí ilẹ̀.

[11] Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí Orebu àti Seebu, àwọn ọmọ-aládé wọn bí Seba àti Salmunna,

[12] tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìní àní pápá oko tútù Ọlọ́run.”

[13] Ìwọ Ọlọ́run, ṣe wọ́n bí ààjà, bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.

[14] Bí iná ti í jó igbó, àti bí ọ̀wọ́-iná ti ń mú òkè ńlá gbiná,

[15] bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle rẹ lépa wọn dẹ́rùbà wọn lójú pẹ̀lú ìjì rẹ.

[16] Fi ìtìjú kún ojú wọn, kí àwọn ènìyàn bá à lè ṣe àfẹ́rí orúkọ rẹ àti kí o fi ìjì líle rẹ dẹ́rùbà, ìwọ Olúwa.

[17] Jẹ́ kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọ́n sì dààmú láéláé kí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn

[18] jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa: pé ìwọ nìkan ní Ọ̀gá-ògo jùlọ lórí gbogbo ayé.

Ìwé Saamu — Chapters