[1] Mó kígbe sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́; mo kígbe sí Ọlọ́run láti gbọ́ tèmi.
[2] Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú, mo wá Olúwa; ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀ ọkàn mí sì kọ̀ láti tù ú nínú.
[3] Èmi rántí rẹ, Ọlọ́run, mo sì kẹ́dùn; mo ṣe àròyé, ẹ̀mí mi sì rẹ̀wẹ̀sì. Sela.
[4] Ìwọ kò fẹ́ kí èmi fi ojú ba oorun, mo dààmú tó bẹ́ẹ̀ tí ń kò le sọ̀rọ̀.
[5] Mo ronú nípa ọjọ́ ìgbàanì; ọdún pípẹ́ sẹ́yìn;
[6] mo rántí orin mi ní òru. Èmi ń bá àyà mi sọ̀rọ̀, ọkàn mi sì ń ṣe àwárí jọjọ.
[7] “Olúwa yóò ha kọ̀ títí láé? Ki yóò ha ṣe ojúrere rẹ̀ mọ́?
[8] Ṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti àánú rẹ̀ ti kú lọ láéláé? Ìlérí rẹ̀ ha kùnà títí ayé?
[9] Ọlọ́run ha gbàgbé láti máa ṣàánú? Ní ìbínú rẹ̀, ó ha sé ojúrere rẹ̀ mọ́?” Sela.
[10] Èmi wí pé, “Èyí ní ẹ̀dùn ọkàn mi, pé ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá-ògo jùlọ ti yípadà”.
[11] Èmi ó rántí iṣẹ́ Olúwa: bẹ́ẹ̀ ni, èmi ó rántí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ọjọ́ pípẹ́.
[12] Èmi ṣàṣàrò lórí iṣẹ́ rẹ gbogbo, pẹ̀lú, ènìyàn sì máa sọ̀rọ̀ gbogbo iṣẹ́ agbára rẹ.
[13] Ọlọ́run, ọ̀nà rẹ jẹ́ mímọ́. Ọlọ́run wo ni ó sì tóbi bí Ọlọ́run wa?
[14] Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń ṣe ìyanu; ìwọ fi agbára rẹ hàn nínú àwọn ènìyàn.
[15] Pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ ra àwọn ènìyàn padà, àwọn ọmọ Jakọbu àti Josẹfu. Sela.
[16] Nígbà tí àwọn omi rí Ọlọ́run, nígbà tí àwọn omi rí ọ, ẹ̀rù bà wọ́n, nítòótọ́ ara ibú kò balẹ̀.
[17] Àwọn ojú ọ̀run tú omi sílẹ̀, àwọsánmọ̀ fi àrá dáhùn; ọfà rẹ̀ ń tàn sẹ́yìn àti síwájú.
[18] Àrá rẹ̀ ni a gbọ́ nínú ìjì, ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí gbogbo ayé; ayé bẹ̀rù, wọ́n sì wárìrì.
[19] Ipa rẹ̀ gba Òkun, ọ̀nà rẹ̀ ń bẹ nínú Òkun, ọ̀nà la omi alágbára kọjá ipa rẹ̀ ń bẹ nínú líla omi alágbára kọjá, nítòótọ́ a kò rí ojú ẹsẹ̀ rẹ̀.
[20] Ó tọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nípa ọwọ́ Mose àti Aaroni.