Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 1:32

[1] Ní Juda ni a mọ Ọlọ́run; orúkọ rẹ̀ sì lágbára ní Israẹli

[2] Àgọ́ rẹ̀ wà ní Salẹmu, ibùgbé rẹ̀ ni Sioni.

[3] Níbẹ̀ ni ó ṣẹ́ ọfà, asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. Sela.

[4] Ìwọ ni ògo àti ọlá, ju òkè ńlá ìkógun wọ̀nyí lọ.

[5] A kó àwọn alágídí ọkàn ní ìkógun wọ́n sun oorun ìgbẹ̀yìn wọn; kò sí ọ̀kan nínú àwọn akọni tó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.

[6] Ní ìfibú rẹ, Ọlọ́run Jakọbu, àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.

[7] Ìwọ nìkan ni ó yẹ kí a bẹ̀rù. Ta ló lé dúró níwájú rẹ, nígbà tí ìwọ bá ń bínú?

[8] Ìwọ ń ṣe ìdájọ́ láti ọ̀run, ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ẹ́,

[9] nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run, bá dìde láti ṣe ìdájọ́, láti gba àwọn ẹni ìnilára ilẹ̀ náà. Sela.

[10] Lóòótọ́, ìbínú rẹ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ, ẹni tí ó yọ nínú ìbínú rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara rẹ ni àmùrè.

[11] Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì mú un ṣẹ; kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó tọ́ láti bẹ̀rù.

[12] Ó ké ẹ̀mí àwọn aládé kúrò; àwọn ọba ayé sì ń bẹ̀rù rẹ̀.

Ìwé Saamu — Chapters