Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 1:38

[1] Èmi yóò kókìkí i rẹ, Olúwa, nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí.

[2] Olúwa Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́, ìwọ sì ti wò mí sàn.

[3] Olúwa, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú, mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò.

[4] Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ẹ̀yin olódodo; kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́.

[5] Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀, ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé; ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́, ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.

[6] Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé, “a kì yóò ṣí mi ní ipò padà.”

[7] Nípa ojúrere rẹ, Olúwa, ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára; ìwọ pa ojú rẹ mọ́, àyà sì fò mí.

[8] Sí ọ Olúwa, ni mo ké pè é; àti sí Olúwa ni mo sọkún fún àánú:

[9] “Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi, nínú lílọ sí ihò mi? Eruku yóò a yìn ọ́ bí? Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo rẹ?

[10] Gbọ́, Olúwa, kí o sì ṣàánú fún mi; ìwọ Olúwa, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.”

[11] Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi; ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,

[12] nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́. Ìwọ Olúwa Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.

Ìwé Saamu — Chapters