Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 0:51

[1] Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti, ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè

[2] Juda wà ní ibi mímọ́, Israẹli wà ní ìjọba.

[3] Òkun sì rí i, ó sì wárìrì: Jordani sì padà sẹ́yìn.

[4] Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn.

[5] Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì? Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?

[6] Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò, àti ẹ̀yin òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn?

[7] Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa; ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu

[8] tí ó sọ àpáta di adágún omi, àti òkúta-ìbọn di orísun omi.

Ìwé Saamu — Chapters