Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 0:59

[1] Ẹ máa yin Olúwa. Yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa, ẹ yin orúkọ Olúwa.

[2] Fi ìbùkún fún orúkọ Olúwa láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

[3] Láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀ orúkọ Olúwa ni kí a máa yìn.

[4] Olúwa ga lórí gbogbo orílẹ̀-èdè, àti ògo rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run.

[5] Ta ló dàbí Olúwa Ọlọ́run wa, tí ó gbé ní ibi gíga.

[6] Tí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wò òun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé!

[7] Ó gbé òtòṣì dìde láti inú erùpẹ̀, àti pé ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá.

[8] Kí ó le mú un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àní pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àwọn ènìyàn rẹ̀.

[9] Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé, àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ rẹ̀. Ẹ yin Olúwa.

Ìwé Saamu — Chapters