[1] Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa, jẹ́ kí igbe ẹ̀bẹ̀ mi kí ó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ.
[2] Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ tí èmi wà nínú ìpọ́njú. Dẹ etí rẹ sí mi; nígbà tí mo bá pè, dá mi lóhùn kíákíá.
[3] Nítorí tí ọjọ́ mi run bí èéfín; egungun mi sì jóná bí ààrò.
[4] Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko; mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi.
[5] Nítorí ohùn ìkérora mi, egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran-ara mi.
[6] Èmi dàbí ẹyẹ igún ní ijù: èmi dàbí òwìwí ibi ahoro.
[7] Èmi dìde; èmi dàbí ẹyẹ lórí ilé.
[8] Ní ọjọ́ gbogbo, àwọn ọ̀tá ológoṣẹ́ mi ń gàn mí; àwọn tí ń ṣe ìkanra sí mi ń fi orúkọ mi bú.
[9] Èmi jẹ eérú gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ mi, èmi sì da ohun mímu mi pọ̀ pẹ̀lú omijé.
[10] Nítorí ìbínú ríru rẹ, nítorí ìwọ ti gbé mi sókè, ìwọ sì gbé mi ṣánlẹ̀.
[11] Ọjọ́ mi dàbí òjìji àṣálẹ́ èmi sì rọ bí koríko.
[12] Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, ni yóò dúró láéláé; ìrántí rẹ láti ìran dé ìran.
[13] Ìwọ ó dìde ìwọ ó sì ṣàánú fún Sioni, nítorí ìgbà àti ṣe ojúrere sí i; àkókò náà ti dé.
[14] Nítorí tí àwọn òkúta jẹ́ inú dídùn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ; wọ́n sì káàánú erùpẹ̀ rẹ.
[15] Àwọn kèfèrí yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa, gbogbo ọba ayé yóò máa bẹ̀rù ògo rẹ.
[16] Torí tí Olúwa yóò gbé Sioni ró, yóò farahàn nínú ògo rẹ̀.
[17] Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní; kì yóò sì gan ẹ̀bẹ̀ wọn.
[18] Jẹ́ kí a kọ èyí fún ìran tí ń bọ̀, àwọn ènìyàn tí a kò tí ì dá yóò yin Olúwa:
[19] “Olúwa wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀run wá ni ó bojú wo ayé,
[20] láti gbọ́ ìrora ará túbú, láti tú àwọn tí a yàn sí ikú sílẹ̀.”
[21] Kí a lè sọ orúkọ Olúwa ní Sioni àti ìyìn rẹ̀ ní Jerusalẹmu.
[22] Ní ìgbà tí a kó àwọn ènìyàn àti ìjọba pọ̀ láti máa sìn Olúwa.
[23] Ní ipa ọ̀nà mi, ó rẹ agbára mi sílẹ̀, ó gé ọjọ́ mi kúrú.
[24] Èmi sì wí pé: “Ọlọ́run mi, má ṣe mú mi kúrò ní agbede-méjì ọjọ́ mi; ọdún rẹ̀ ń lọ láti ìran dé ìran.
[25] Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
[26] Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà; gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ. Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọn wọn yóò sì di àpatì.
[27] Ṣùgbọ́n ìwọ wà digbí síbẹ̀, ọdún rẹ kò sì ní òpin.
[28] Àwọn ọmọ ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò dúró ní iwájú rẹ pẹ́; a ó sì fi ẹsẹ̀ irú-ọmọ wọn sọlẹ̀ ní iwájú rẹ.”