Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 4:04

[1] Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi. Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ; ọlá àti ọláńlá ni ìwọ wọ̀ ní aṣọ.

[2] Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣọ; ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní,

[3] ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi àjà ìyẹ̀wù rẹ. Ìwọ tí o ṣe àwọsánmọ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun rẹ ìwọ tí ó ń rìn lórí apá ìyẹ́ afẹ́fẹ́.

[4] Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ, ọ̀wọ́-iná ni àwọn olùránṣẹ́ rẹ.

[5] O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀; tí a kò le è mì láéláé.

[6] Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ; àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá.

[7] Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí rẹ ni àwọn omi lọ, nípa ohùn àrá rẹ ni wọ́n sálọ.

[8] wọ́n sàn kọjá lórí àwọn òkè, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀, sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn.

[9] Ìwọ gbé òpin tí wọn kò lè kọjá rẹ̀ kálẹ̀; láéláé ni wọ́n kò ní lè bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.

[10] Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn àfonífojì; tí ó ń sàn láàrín àwọn òkè.

[11] Wọ́n fún gbogbo àwọn ẹranko igbó ní omi àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ń pa òǹgbẹ wọn.

[12] Àwọn ẹyẹ ojú òfúrufú tẹ́ ìtẹ́ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi wọ́n ń kọrin láàrín àwọn ẹ̀ka.

[13] Ó bu omi rin àwọn òkè láti ìyẹ̀wù rẹ̀ wá; a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èso iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

[14] Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹ àti àwọn ewébẹ̀ fún ènìyàn láti lò, kí ó lè mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá.

[15] Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀, òróró láti mú ojú rẹ̀ tan, àti àkàrà láti ra ọkàn rẹ̀ padà.

[16] Àwọn igi Olúwa ni a bu omi rin dáradára, kedari ti Lebanoni tí ó gbìn.

[17] Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọn bí ó ṣe tí àkọ̀ ni, orí igi gíga ni ilé rẹ̀.

[18] Àwọn òkè gíga ni ààbò fún àwọn ewúrẹ́ igbó; àti àwọn àlàpà jẹ́ ààbò fún àwọn ehoro.

[19] Òṣùpá jẹ́ àmì fún àkókò oòrùn sì mọ ìgbà tí yóò wọ̀.

[20] Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru, nínú èyí tí gbogbo ẹranko igbó ń rìn kiri.

[21] Kìnnìún ń bú ramúramù fún ohun ọdẹ wọn wọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

[22] Oòrùn ràn, wọ́n sì kó ara wọn jọ, wọn padà lọ dùbúlẹ̀ sí ihò wọn.

[23] Ọkùnrin jáde lọ sí iṣẹ́ wọn, àti sí làálàá rẹ̀ títí di àṣálẹ́.

[24] Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, Olúwa! Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn: ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ.

[25] Bẹ́ẹ̀ ni Òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú, tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìsàlẹ̀ láìníye ohun alààyè tí tóbi àti kékeré.

[26] Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn, àti Lefitani, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú rẹ̀.

[27] Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́ láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò rẹ̀.

[28] Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn, wọn yóò kó jọ; nígbà tí ìwọ bá la ọwọ́ rẹ̀, a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere.

[29] Nígbà tí ìwọ bá pa ojú rẹ mọ́ ara kò rọ̀ wọ́n nígbà tí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn lọ, wọn ó kú, wọn ó sì padà sí erùpẹ̀.

[30] Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí rẹ, ni a dá wọn, ìwọ sì tún ojú ayé ṣe.

[31] Jẹ́ kí ògo Olúwa wà pẹ́ títí láé; kí inú Olúwa kí ó dùn ní ti iṣẹ́ rẹ̀,

[32] ẹni tí ó wo ayé, tí ó sì wárìrì, ẹni tí ó fọwọ́ tọ́ àwọn òkè, tí wọ́n yọ èéfín.

[33] Ní gbogbo ayé mi ní n ó kọrin sí Olúwa: èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè.

[34] Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ mi kí ó tẹ́ ọ lọ́rùn bí mo ti ń yọ̀ nínú Olúwa.

[35] Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kúrò láyé kí ènìyàn búburú má sì sí mọ́. Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi. Yin Olúwa.

Ìwé Saamu — Chapters