Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 1:53

[1] Kì í ṣe fún wa, Olúwa kì í ṣe fún wa, ṣùgbọ́n fún orúkọ rẹ ni a fi ògo fún, fún àánú àti òtítọ́ rẹ.

[2] Torí kí ni àwọn kèfèrí yóò ṣe sọ pé, níbo ni Ọlọ́run wa wà.

[3] Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run: tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.

[4] Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà, iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni.

[5] Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀, wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.

[6] Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀: wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbóòórùn.

[7] Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó, wọ́n ní ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn; bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn.

[8] Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.

[9] Ìwọ Israẹli gbẹ́kẹ̀lé Olúwa: òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn

[10] Ẹ̀ yin ilé Aaroni, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa: òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn.

[11] Ẹ̀ yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa: òun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn.

[12] Olúwa tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé Israẹli; yóò bùkún ilé Aaroni.

[13] Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa, àti kékeré àti ńlá.

[14] Olúwa yóò mú ọ pọ̀ sí i síwájú àti síwájú, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀.

[15] Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

[16] Ọ̀run àní ọ̀run ni ti Olúwa: ṣùgbọ́n ayé ló fi fún ọmọ ènìyàn.

[17] Òkú kò lè yìn Olúwa, tàbí ẹni tí ó ti lọ sí ìsàlẹ̀ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́.

[18] Ṣùgbọ́n àwa ó fi ìbùkún fún Olúwa láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé. Ẹ yin Olúwa.

Ìwé Saamu — Chapters