Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 1:19

[1] Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́, ìwọ Ọlọ́run òdodo mi. Fún mi ní ìdáǹdè nínú ìpọ́njú mi; ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.

[2] Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú? Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá ọlọ́run èké?

[3] Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀; Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.

[4] Ẹ bínú ẹ má ṣe ṣẹ̀, nígbà tí ẹ bá wà lórí ibùsùn yín, ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀, kí ó sì dákẹ́ jẹ́.

[5] Ẹ rú ẹbọ òdodo kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

[6] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè pé, “Ta ni yóò ṣe rere fún wa?” Olúwa, jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí wa lára,

[7] Ìwọ ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi ju ìgbà tí hóró irúgbìn àti wáìnì tuntun wọ́n pọ̀ fún mi lọ.

[8] Èmi yóò dùbúlẹ̀, èmi ó sì sùn ní àlàáfíà, nítorí ìwọ nìkan, Olúwa, ni o mú mi gbé láìléwu.

Ìwé Saamu — Chapters