Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 0:38

[1] Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí, ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run.

[2] Kíyèsi, bí ojú àwọn ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn, àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa, títí yóò fi ṣàánú fún wa.

[3] Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa; nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀.

[4] Ọkàn wa kún púpọ̀ fún ẹ̀gàn àwọn onírera, àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.

Ìwé Saamu — Chapters