Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 1:25

[1] Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa, nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi, mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa, ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.

[2] Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa, kí o sì dán mi wò, dán àyà àti ọkàn mi wò;

[3] nítorí ìfẹ́ ẹ̀ rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi, èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.

[4] Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé.

[5] Èmi ti kórìíra àwùjọ àwọn ènìyàn búburú èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.

[6] Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ rẹ ká Olúwa.

[7] Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́, èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.

[8] Háà Olúwa, èmí ń fẹ́ ilé rẹ níbi tí ìwọ ń gbé, àní níbi tí ògo rẹ̀ wà.

[9] Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ,

[10] àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

[11] Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́; rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi.

[12] Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú; nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún Olúwa.

Ìwé Saamu — Chapters