[1] Ọkàn mi mọ ọ̀rọ̀ rere gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń sọ ohun tí mo ti ṣe fún ọba ahọ́n mi ni kálámù ayára kọ̀wé.
[2] Ìwọ yanjú ju àwọn ọmọ ènìyàn lọ: a da oore-ọ̀fẹ́ sí ọ ní ètè: nítorí náà ni Ọlọ́run ṣe bùkún fún ọ láéláé.
[3] Gba idà rẹ mọ́ ìhà rẹ, ìwọ alágbára jùlọ wọ ara rẹ ní ògo àti ọláńlá.
[4] Nínú ọláńlá rẹ, máa gẹṣin lọ ní àlàáfíà lórí òtítọ́, ìwà tútù àti òtítọ́; jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ohun ẹ̀rù.
[5] Jẹ́ kí ọfà mímú rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lu jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
[6] Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ, ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni.
[7] Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburú nígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run rẹ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ, nípa fífi àmì òróró ayọ̀ kùn ọ́.
[8] Gbogbo aṣọ rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjìá àti aloe àti kasia; láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú rẹ̀ dùn.
[9] Àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba wà nínú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀, ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúró nínú wúrà Ofiri.
[10] Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí rẹ sí mi gbàgbé àwọn ènìyàn rẹ àti ilé baba rẹ.
[11] Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà rẹ gidigidi nítorí òun ni olúwa rẹ kí ìwọ sì máa tẹríba fún un.
[12] Ọmọbìnrin ọba Tire yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùn àwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojúrere rẹ̀.
[13] Gbogbo ògo ni ti ọmọbìnrin ọba ní àárín ilé rẹ̀, iṣẹ́ wúrà ọnà abẹ́rẹ́ ní aṣọ rẹ̀.
[14] Nínú aṣọ olówó iyebíye ni a mú un tọ́ ọba wá, àwọn wúńdíá ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ̀lé e, wọ́n sí mú un tọ̀ ọ́ wá.
[15] Wọ́n sì mú un wá pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn wọ́n sì wọ ààfin ọba.
[16] Ọmọ rẹ̀ ni yóò gba ipò baba rẹ̀ ìwọ yóò sì fi wọ́n joyè lórí ilẹ̀ gbogbo.
[17] Èmí yóò máa rántí orúkọ rẹ̀ ní ìran gbogbo, nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò yìn ọ́ láé àti láéláé.