Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 2:54

[1] Nítòótọ́ Ọlọ́run dára fún Israẹli, fún àwọn ọlọ́kàn funfun.

[2] Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán; ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán.

[3] Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣe féfé nígbà tí mo bá rí àlàáfíà àwọn ènìyàn búburú.

[4] Wọn kò ṣe wàhálà; ara wọn mókun wọn sì lágbára.

[5] Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn; a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlòmíràn.

[6] Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn; ìwà ipá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ.

[7] Láti inú ọkàn àrékérekè ni àìṣòdodo ti wá; ẹ̀rí ọkàn búburú wọn kò ní òdínwọ̀n.

[8] Wọn ń ṣẹ̀sín, wọn sì ń sọ̀rọ̀-òdì ní ti ìnilára, wọ́n ń sọ̀rọ̀ láti ibi gíga.

[9] Wọ́n ń gbé ẹ̀mí wọn lé ọ̀run ahọ́n wọn gba ipò ayé.

[10] Nítorí náà àwọn ènìyàn wọn yípadà sí wọn wọ́n sì mu omi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

[11] Wọ́n wí pé, “Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe mọ̀? Ọ̀gá-ògo ha ní ìmọ̀ bí?”

[12] Bí àwọn ènìyàn búburú ṣe rí nìyí, ènìyàn asán, wọ́n ń pọ̀ ní ọrọ̀.

[13] Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́; nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀.

[14] Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu; a sì ń jẹ mí ní yà ní gbogbo òwúrọ̀.

[15] Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,” èmi ó ṣẹ̀ sí ìran àwọn ọmọ rẹ̀.

[16] Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí, Ó jẹ́ ìnilára fún mi,

[17] títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run; nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi.

[18] Lóòtítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́ ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun.

[19] Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìí bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan! Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọ́n pátápátá!

[20] Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí, bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, Olúwa, ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn.

[21] Nígbà tí inú mi bàjẹ́ àti ọkàn mi ṣì korò,

[22] mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye; mo jẹ́ ẹranko ní iwájú rẹ.

[23] Síbẹ̀ mo wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo; ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.

[24] Ìwọ fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi ní ìkẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo.

[25] Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ? Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn rẹ.

[26] Ara mi àti ọkàn mi le è kùnà ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi àti ìpín mi títí láé.

[27] Àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóò ṣègbé ìwọ ti pa gbogbo wọn run; tí ń ṣe àgbèrè kiri kúrò lọ́dọ̀ rẹ.

[28] Ṣùgbọ́n ní ti èmi, ó dára láti súnmọ́ Ọlọ́run. Èmi ti fi Olúwa Olódùmarè ṣe ààbò mi; kí èmi ó lè máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ.

Ìwé Saamu — Chapters