Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 0:43

[1] Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà, àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.

[2] Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín, àti ahọ́n wa kọ orin; nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé, Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.

[3] Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa; nítorí náà àwa ń yọ̀.

[4] Olúwa mú ìkólọ wa padà, bí ìṣàn omi ní gúúsù.

[5] Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn yóò fi ayọ̀ ka.

[6] Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ, tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́, lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá, yóò sì ru ìtí rẹ̀.

Ìwé Saamu — Chapters