Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 1:55

[1] Olúwa, rántí Dafidi nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.

[2] Ẹni tí ó ti búra fún Olúwa, tí ó sì ṣe ìlérí fún alágbára Jakọbu pé.

[3] Nítòótọ́, èmi kì yóò wọ inú àgọ́ ilé mi lọ, bẹ́ẹ̀ èmi kì yóò gun orí àkéte mi.

[4] Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi, tàbí òògbé fún ìpéǹpéjú mi,

[5] títí èmi ó fi rí ibi fún Olúwa, ibùjókòó fún alágbára Jakọbu.

[6] Kíyèsi i, àwa gbúròó rẹ̀ ni Efrata: àwa rí i nínú oko ẹgàn náà.

[7] Àwa ó lọ sínú àgọ́ rẹ̀: àwa ó máa sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀

[8] Olúwa, dìde sí ibi ìsinmi rẹ: ìwọ, àti àpótí agbára rẹ.

[9] Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà rẹ: kí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ kí ó máa hó fún ayọ̀.

[10] Nítorí tí Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀, má ṣe yí ojú ẹni òróró rẹ padà.

[11] Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dafidi, Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀, nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ.

[12] Bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́ àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn, àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ láéláé.

[13] Nítorí tí Olúwa ti yan Sioni: ó ti fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀.

[14] Èyí ni ibi ìsinmi mi láéláé: níhìn-ín ni èmi yóò máa gbé: nítorí tí mo fẹ́ ẹ.

[15] Èmi yóò bùkún oúnjẹ rẹ̀ púpọ̀púpọ̀: èmi yóò fi oúnjẹ tẹ́ àwọn tálákà rẹ̀ lọ́rùn.

[16] Èmi yóò sì fi ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà rẹ̀: àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ yóò máa hó fún ayọ̀.

[17] Níbẹ̀ ni èmi yóò gbé mú ìwo Dafidi yọ̀, èmi ti ṣe ìlànà fìtílà kan fún ẹni òróró mi.

[18] Àwọn ọ̀tá rẹ̀ ni èmi yóò fi ìtìjú wọ̀: ṣùgbọ́n lára òun tìkára rẹ̀ ni adé yóò máa gbilẹ̀.

Ìwé Saamu — Chapters