Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 1:05

[1] Gbà mí, Ọlọ́run nípa orúkọ rẹ: dá mi láre nípa agbára rẹ.

[2] Gbọ́ àdúrà mi, Ọlọ́run; fi etí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

[3] Àwọn agbéraga àlejò dìde sí mí. Àwọn aninilára sì ń wá mi láti pa, àwọn ẹni tí kò ka Ọlọ́run sí ní ojú wọn.

[4] Kíyèsi i Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ mi; Olúwa ní ẹni tí ó mú mi dúró, pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.

[5] Jẹ́ kí ibi padà sẹ́yìn sí àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi; pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.

[6] Èmí yóò rú ẹbọ àtinúwá sí ọ, èmi yóò yin orúkọ rẹ, Olúwa, nítorí tí ó dára.

[7] Nítorí tí ó yọ mí kúrò nínú ibi gbogbo ojú mi ti wo ìṣẹ́gun lórí ọ̀tá mi.

Ìwé Saamu — Chapters