[1] Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́ṣẹ̀, ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa.
[2] Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́ tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.
[3] Wọn kò ṣe ohun tí kò dára; wọ́n rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
[4] Ìwọ ti la ìlànà rẹ̀ sílẹ̀ kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi.
[5] Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣin láti máa pa òfin rẹ̀ mọ́!
[6] Nígbà náà, ojú kò ní tì mí nígbà tí mo bá ń kíyèsi àṣẹ rẹ̀ gbogbo.
[7] Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣin bí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo rẹ̀.
[8] Èmi yóò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀, má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátápátá.
[9] Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ yóò ti ṣe pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́? Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ rẹ.
[10] Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi má ṣe jẹ́ kí èmi yapa kúrò nínú àṣẹ rẹ.
[11] Èmi ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ ní ọkàn mi kí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ.
[12] Ìyìn ni fún Olúwa; kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
[13] Pẹ̀lú ètè mi èmi tún ṣírò gbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu rẹ.
[14] Èmi ń yọ̀ ní ọ̀nà ẹ̀rí rẹ, bí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọláńlá.
[15] Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà rẹ èmi sì kíyèsi ọ̀nà rẹ.
[16] Inú mi dùn sí àṣẹ rẹ; èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà rẹ.
[17] Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ, èmi yóò sì wà láààyè; èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ.
[18] La ojú mi kí èmi lè ríran rí ohun ìyanu tí ó wà nínú òfin rẹ.
[19] Àlejò ní èmi jẹ́ láyé, má ṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fún mi.
[20] Ọkàn mi pòruurù pẹ̀lú ìfojúsọ́nà nítorí òfin rẹ nígbà gbogbo.
[21] Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn ún tí ó ṣìnà kúrò nínú àṣẹ rẹ.
[22] Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi, nítorí èmi pa òfin rẹ mọ́.
[23] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọpọ̀, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi, ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ rẹ.
[24] Òfin rẹ ni dídùn inú mi; àwọn ní olùbádámọ̀ràn mi.
[25] Ọkàn mí lẹ̀ mọ́ erùpẹ̀; ìwọ sọ mí di ààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
[26] Èmi tún ọ̀nà mi ṣírò ìwọ sì dá mi lóhùn; kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
[27] Jẹ́ kí n mọ ẹ̀kọ́ ìlànà rẹ: nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu rẹ.
[28] Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́; fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
[29] Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tàn fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ nípa òfin rẹ.
[30] Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́ èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin rẹ.
[31] Èmi yára di òfin rẹ mú. Olúwa má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
[32] Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ, nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀.
[33] Kọ́ mi, Olúwa, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ; nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.
[34] Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́ èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi.
[35] Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí, nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.
[36] Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́.
[37] Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán: pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
[38] Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ, nítorí òfin rẹ dára.
[39] Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára.
[40] Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ! Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ.
[41] Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, Olúwa, ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
[42] Nígbà náà ni èmi yóò dá ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn, nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
[43] Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ.
[44] Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo láé àti láéláé.
[45] Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira, nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde.
[46] Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba ojú kì yóò sì tì mí,
[47] nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn.
[48] Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn, èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀.
[49] Rántí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ, nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí.
[50] Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí: ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́.
[51] Àwọn agbéraga fi mí ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró, ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin rẹ.
[52] Èmi rántí àwọn òfin rẹ ìgbàanì, Olúwa, èmi sì rí ìtùnú nínú wọn.
[53] Ìbínú dì mímú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú, tí wọ́n ti kọ òfin rẹ sílẹ̀.
[54] Òfin rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi níbikíbi tí èmi ń gbé.
[55] Ní òru èmi rántí orúkọ rẹ, Olúwa, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
[56] nítorí tí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ gbọ́.
[57] Ìwọ ni ìpín mi, Olúwa: èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ.
[58] Èmi ti wá ojú rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi: fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
[59] Èmi ti kíyèsi ọ̀nà mi èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin rẹ.
[60] Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
[61] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn, èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
[62] Ní àárín ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ nítorí òfin òdodo rẹ.
[63] Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ rẹ.
[64] Ayé kún fún ìfẹ́ rẹ, Olúwa, kọ́ mi ní òfin rẹ.
[65] Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa.
[66] Kọ́ mi ní ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere, nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ rẹ.
[67] Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà, ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ.
[68] Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni; kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
[69] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti gbìmọ̀ èké sí mí, èmi pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.
[70] Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú, ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin rẹ.
[71] Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ.
[72] Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọ ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ.
[73] Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi tí ó sì mọ mí; fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ rẹ.
[74] Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ máa yọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí mi, nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
[75] Èmi mọ, Olúwa, nítorí òfin rẹ òdodo ni, àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú.
[76] Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi, gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ.
[77] Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè, nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi.
[78] Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraga nítorí wọn pa mí lára láìnídìí ṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
[79] Kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yí padà sí mi, àwọn tí ó ní òye òfin rẹ.
[80] Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin rẹ, kí ojú kí ó má ṣe tì mí.
[81] Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ, ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
[82] Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wíwo ìpinnu rẹ; èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?”
[83] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí awọ-wáìnì lójú èéfín, èmi kò gbàgbé ìlànà rẹ.
[84] Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó? Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí mi wí?
[85] Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi, tí ó lòdì sí òfin rẹ.
[86] Gbogbo àṣẹ rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé; ràn mí lọ́wọ́, nítorí ènìyàn ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí.
[87] Wọ́n fẹ́rẹ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé, ṣùgbọ́n èmi kò kọ ẹ̀kọ́ rẹ.
[88] Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ, èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu rẹ̀ gbọ́.
[89] Ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa, títí láé ni; ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run.
[90] Òtítọ́ rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran; ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin.
[91] Òfin rẹ dúró di òní nítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́.
[92] Bí òfin rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi, èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.
[93] Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ láé, nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́.
[94] Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹ èmi ti wá ẹ̀kọ́ rẹ.
[95] Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run, ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsi ẹ̀rí rẹ.
[96] Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin; ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ aláìlópin ni.
[97] Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó! Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.
[98] Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ, nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé.
[99] Èmi ní iyè inú ju gbogbo olùkọ́ mi lọ, nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin rẹ.
[100] Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ, nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.
[101] Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ rẹ.
[102] Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ, nítorí ìwọ fúnra rẹ̀ ni ó kọ́ mi.
[103] Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó, ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi!
[104] Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ; nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.
[105] Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà sí ẹsẹ̀ mi àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi.
[106] Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọn wí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo rẹ.
[107] A pọ́n mi lójú gidigidi; Olúwa, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ
[108] Olúwa, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi, kí o sì kọ́ mi ní òfin rẹ̀.
[109] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ mi nígbà gbogbo, èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
[110] Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n èmi kò ṣìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
[111] Òfin rẹ ni ogún mi láéláé; àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi.
[112] Ọkàn mi ti lé pípa òfin rẹ mọ́ láé dé òpin.
[113] Èmi kórìíra àwọn ọlọ́kàn méjì, ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin rẹ.
[114] Ìwọ ni ààbò mi àti asà mi; èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
[115] Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú, kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́!
[116] Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, kí èmi kí ó lè yè Má sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí.
[117] Gbé mi sókè, èmí yóò sì wa láìléwu; nígbà gbogbo ni èmi yóò máa júbà òfin rẹ.
[118] Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó ṣìnà kúrò nínú òfin rẹ, nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni.
[119] Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọ yọ kúrò bí i ìdàrọ́; nítorí náà, èmi fẹ́ òfin rẹ̀.
[120] Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí rẹ̀: èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin rẹ.
[121] Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́: má ṣe fi mí sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára.
[122] Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ dájú: má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára.
[123] Ojú mi kùnà, fún wíwo ìgbàlà rẹ, fún wíwo ìpinnu òdodo rẹ.
[124] Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ kí o sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
[125] Èmi ni ìránṣẹ́ rẹ; ẹ fún mi ní òye kí èmi lè ní òye òfin rẹ
[126] Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, Olúwa; nítorí òfin rẹ ti fọ́.
[127] Nítorí èmi fẹ́ràn àṣẹ rẹ ju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ,
[128] nítorí èmi kíyèsi gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ rẹ̀, èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú.
[129] Òfin rẹ̀ ìyanu ni: nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́.
[130] Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá; ó fi òye fún àwọn òpè.
[131] Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ, nítorí èmi fojú ṣọ́nà sí àṣẹ rẹ.
[132] Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi, bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ.
[133] Fi ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ, má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi.
[134] Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn, kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.
[135] Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ rẹ lára kí ó sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
[136] Omijé sàn jáde ní ojú mi, nítorí wọn kò gba pé òfin rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.
[137] Olódodo ni ìwọ Olúwa ìdájọ́ rẹ sì dúró ṣinṣin.
[138] Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo: wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.
[139] Ìtara mi ti pa mí run, nítorí àwọn ọ̀tá mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ rẹ dá.
[140] Wọ́n ti dán ìpinnu rẹ wò pátápátá ìránṣẹ́ rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.
[141] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ.
[142] Òdodo rẹ wà títí láé òtítọ́ ni òfin rẹ̀.
[143] Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi, ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ ni inú dídùn mi.
[144] Òfin rẹ jẹ́ òtítọ́ láé; fún mi ní òye kí èmi lè yè.
[145] Èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi: dá mi lóhùn Olúwa, èmi yóò sì gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
[146] Èmi kígbe pè ọ́; gbà mí èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́.
[147] Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìrànlọ́wọ́; èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
[148] Ojú mi ṣáájú ìṣọ́ òru, nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ.
[149] Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ: pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
[150] Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòsí, ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin rẹ.
[151] Síbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, Olúwa, àti gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òtítọ́.
[152] Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin rẹ tí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé.
[153] Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí, nítorí èmi kò gbàgbé òfin rẹ.
[154] Gba ẹjọ́ mi rò kí o sì rà mí padà; pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
[155] Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburú nítorí wọn kò wá àṣẹ rẹ.
[156] Ìyọ́nú rẹ̀ tóbi, Olúwa; pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
[157] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀tá tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi, ṣùgbọ́n èmi kò tí ì yípadà kúrò nínú òfin rẹ.
[158] Èmi wo àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́ nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́.
[159] Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ rẹ; pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ.
[160] Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ; gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni.
[161] Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí, ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ.
[162] Èmi yọ̀ nínú ìpinnu rẹ bí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀.
[163] Èmi kórìíra mo sì kọ èké ṣíṣe ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin rẹ.
[164] Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́ nítorí òfin òdodo rẹ.
[165] Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin rẹ, kò sì ṣí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.
[166] Èmi yóò dúró de ìgbàlà rẹ, Olúwa, èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ.
[167] Èmi gba òfin rẹ gbọ́, nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀púpọ̀.
[168] Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ rẹ àti òfin rẹ, nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi.
[169] Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú rẹ, Olúwa; fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
[170] Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú rẹ; gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
[171] Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde, nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
[172] Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ, nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo.
[173] Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣetán láti ràn mí lọ́wọ́, nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ rẹ.
[174] Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, Olúwa, àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi.
[175] Jẹ́ kí èmi wà láààyè ki èmi lè yìn ọ́, kí o sì jẹ́ kí òfin rẹ mú mi dúró.
[176] Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó sọnù. Wá ìránṣẹ́ rẹ, nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.