[1] Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú, kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;
[2] nítorí pé wọn yóò gbẹ bí i koríko, wọn yóò sì rẹ̀ dànù bí ewéko tútù.
[3] Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, kí o sì máa ṣe rere; torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀.
[4] Ṣe inú dídùn sí Olúwa; òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀.
[5] Fi ọ̀nà rẹ lé Olúwa lọ́wọ́; gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é.
[6] Yóò sì mú kí òdodo rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, àti ìdájọ́ rẹ̀ bí ọ̀sán gangan.
[7] Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa, kí o sì fi sùúrù dúró dè é; má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn, nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ.
[8] Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkáàánú sílẹ̀, má ṣe ṣe ìkanra, kí ó má ba à ṣé búburú pẹ̀lú.
[9] Nítorí tí á ó gé àwọn olùṣe búburú kúrò, ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de Olúwa àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà.
[10] Síbẹ̀ nígbà díẹ̀ sí i, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ̀; nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, wọn kì yóò sí níbẹ̀.
[11] Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ilẹ̀ náà, wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.
[12] Ènìyàn búburú di rìkíṣí sí olóòtítọ́, wọ́n sì pa eyín wọn keke sí wọn;
[13] ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú, nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀.
[14] Ènìyàn búburú fa idà yọ, wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn, láti sọ tálákà àti aláìní kalẹ̀, láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin.
[15] Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ, àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́.
[16] Ohun díẹ̀ tí olódodo ní, sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú;
[17] nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n Olúwa gbé olódodo sókè.
[18] Olúwa mọ àwọn ọjọ́ àwọn tó dúró ṣinṣin, àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé.
[19] Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi, àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn.
[20] Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé. Àwọn ọ̀tá Olúwa yóò dàbí ẹwà oko tútù; wọn fò lọ; bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò.
[21] Àwọn ènìyàn búburú yá, wọn kò sì san án padà, ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa ṣàánú, a sì máa fi fún ni;
[22] nítorí àwọn tí Olúwa bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà, àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò.
[23] Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, o sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀;
[24] bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá, nítorí tí Olúwa di ọwọ́ rẹ̀ mú.
[25] Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà; síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀, tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ.
[26] Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni; a sì máa bùsi i fún ni.
[27] Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere; nígbà náà ni ìwọ yóò gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé.
[28] Nítorí pé Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́, kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn olódodo ni a ó pamọ́ títí ayérayé, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburú ni a ó ké kúrò.
[29] Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà, yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé.
[30] Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n, ahọ́n rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́.
[31] Òfin Ọlọ́run rẹ̀ ń bẹ ní àyà wọn; àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ kì yóò yẹ̀.
[32] Ènìyàn búburú ń ṣọ́ olódodo, Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á.
[33] Olúwa kì yóò fi lé e lọ́wọ́ kì yóò sì dá a lẹ́bi, nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.
[34] Dúró de Olúwa, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́. Yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ilẹ̀ náà; nígbà tí a bá gé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri.
[35] Èmi ti rí ènìyàn búburú tí ń hu ìwà ìkà, ó sì fi ara rẹ̀ gbilẹ̀ bí igi tútù ńlá,
[36] ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan sí i ó kọjá lọ, sì kíyèsi, kò sì sí mọ́; bi ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé mo wá a kiri, ṣùgbọ́n a kò le è ri.
[37] Máa kíyèsi ẹni pípé, kí o sì wo ẹni tó dúró ṣinṣin; nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà.
[38] Ṣùgbọ́n àwọn olùrékọjá ni a ó parun papọ̀; ìran àwọn ènìyàn búburú ni a ó gé kúrò.
[39] Ìgbàlà àwọn onídùúró ṣinṣin wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa; òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú
[40] Olúwa yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ yóò sì gbà wọ́n; yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú, yóò sì gbà wọ́n là, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.