[1] Ọgbọ́n ti kọ́ ilé rẹ̀, ó ti gbẹ́ òpó o rẹ̀ méjèèjì,
[2] ó ti fi ilé pọn tí, ó ti fọ̀nà rokà. Ó sì ti ṣètò o tábìlì oúnjẹ rẹ̀
[3] ó ti rán àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ jáde, ó sì ń pè, láti ibi tí ó ga jù láàrín ìlú.
[4] “Jẹ́ kí gbogbo àwọn aláìgbọ́n wọ ibí wá!” Ó ń wí fún àwọn tí kò lọ́gbọ́n pé,
[5] “Wá, ẹ wá jẹ́ oúnjẹ mi sì mu wáìnì tí mo ti pò.
[6] Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè; rìn ní ọ̀nà òye.
[7] “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú.
[8] Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ. Bá ọlọ́gbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ;
[9] kọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì gbọ́n sí i kọ́ olódodo ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì fi kún ìmọ̀ rẹ̀.
[10] “Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ nípa Ẹni Mímọ́ ni òye.
[11] Nítorí nípasẹ̀ mi ọjọ́ rẹ yóò gùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò sì kún ọjọ́ ayé rẹ.
[12] Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè: bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà.”
[13] Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo; ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìní ìmọ̀.
[14] Ó jókòó ní ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀ lórí ìjókòó níbi tí ó ga jù láàrín ìlú,
[15] ó ń pe àwọn tí ó ń kọjá lọ, tí wọn ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn.
[16] “Jẹ́ kí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ aláìlóye súnmọ́ bí!” Ni ó wí fún ẹni tí òye kù díẹ̀ ká à tó fún.
[17] “Omi tí a jí mu dùn oúnjẹ tí a jẹ ní ìkọ̀kọ̀ a máa ládùn!”
[18] Ṣùgbọ́n wọn ò funra pé àwọn òkú wà níbẹ̀, pé àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ isà òkú.