[1] Ọmọ mi, bí ìwọ bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ sí inú rẹ,
[2] tí ìwọ dẹtí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n tí ìwọ sì fi ọkàn rẹ sí òye,
[3] àní, bí ìwọ bá ké tọ ìmọ̀ lẹ́yìn, tí ìwọ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye
[4] bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀ bí i fàdákà tí ìwọ sì wa kiri bí ìṣúra tí a fi pamọ́.
[5] Nígbà náà ni ìwọ yóò bẹ̀rù Olúwa, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.
[6] Nítorí Olúwa ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n, láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá.
[7] Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo, Òun ni asà fún àwọn tí ń rìn déédé,
[8] Ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́ Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́.
[9] Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ òdodo àti ìdájọ́, àti àìṣègbè—gbogbo ipa ọ̀nà rere.
[10] Nítorí ọgbọ́n yóò wọ inú ọkàn rẹ ìmọ̀ yóò sì jẹ́ ìtura fún ọkàn rẹ.
[11] Ìmòye yóò pa ọ mọ́ òye yóò sì máa ṣọ́ ọ.
[12] Ọgbọ́n yóò gbà ọ́ là kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú, lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí ọrọ̀ ọ wọn jẹ́ àyídáyidà,
[13] ẹni tí ó kúrò ní ọ̀nà ìdúró ṣinṣin láti rìn ní ọ̀nà tí ó ṣókùnkùn,
[14] ẹni tí ó yọ̀ nínú ṣíṣe búburú, tí ó ṣe inú dídùn sí àyídáyidà àwọn ènìyàn ibi,
[15] ọ̀nà ẹni tí ó wọ́ tí wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ní ọ̀nà wọn.
[16] Yóò gba ìwọ pẹ̀lú là kúrò lọ́wọ́ àwọn àjèjì obìnrin, àní, lọ́wọ́ obìnrin àjèjì tí ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ tannijẹ,
[17] ẹni tí ó ti kọ ọkọ àkọ́fẹ́ ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì gbàgbé májẹ̀mú tí ó ti dá níwájú Ọlọ́run rẹ̀.
[18] Nítorí ilé rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà sí ikú ipa ọ̀nà rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn òkú.
[19] Kò sẹ́ni tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó padà bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í dé ọ̀nà ìyè.
[20] Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rere kí ìwọ kí ó sì pa ọ̀nà àwọn olódodo mọ́.
[21] Nítorí ẹni dídúró ṣinṣin yóò gbé ní ilé náà àwọn aláìlẹ́gàn sì ni yóò máa wà nínú rẹ̀.
[22] Ṣùgbọ́n a ó ké ènìyàn búburú kúrò lórí ilẹ̀ náà a ó sì fa àwọn aláìṣòótọ́ tu kúrò lórí rẹ̀.