Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 2:44

[1] Ọlọ́gbọ́n ọmọ gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹlẹ́gàn kò gbọ́ ìbáwí.

[2] Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ènìyàn ń gbádùn ohun rere, ṣùgbọ́n, ìfẹ́ ọkàn aláìṣòótọ́ ní ìwà ipá.

[3] Ẹnikẹ́ni tí ó ṣọ́ ẹnu rẹ̀ pa ẹnu ara rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ gbàù gbàù yóò parun.

[4] Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́, ṣùgbọ́n kò rí nǹkan kan, ṣùgbọ́n ọkàn àwọn ti kì í ṣe ọ̀lẹ rí ìtẹ́lọ́rùn.

[5] Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú.

[6] Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòtítọ́ inú, ṣùgbọ́n ìwà búburú ṣí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ipò.

[7] Ènìyàn kan díbọ́n bí ẹni tí ó ní ọrọ̀ síbẹ̀ kò ní nǹkan kan ẹlòmíràn díbọ́n bí i tálákà, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

[8] Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀ ṣùgbọ́n tálákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà.

[9] Ìmọ́lẹ̀ olódodo tàn roro, ṣùgbọ́n fìtílà ènìyàn búburú ni a pa kú.

[10] Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ ni ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn.

[11] Owó tí a fi ọ̀nà èrú kójọ yóò ṣí lọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀díẹ̀ yóò pọ̀ sí i.

[12] Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀ ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè.

[13] Ẹni tí ó kẹ́gàn ẹ̀kọ́ yóò jìyà rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa àṣẹ mọ́ gba èrè rẹ̀.

[14] Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹ̀kùn ikú.

[15] Òye pípé ń mú ni rí ojúrere, ṣùgbọ́n ọ̀nà aláìṣòótọ́ kì í tọ́jọ́.

[16] Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀, ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.

[17] Ìránṣẹ́ búburú bọ́ sínú ìdààmú ṣùgbọ́n aṣojú olóòtítọ́ mú ìwòsàn wá.

[18] Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di tálákà yóò sì rí ìtìjú, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá.

[19] Ìfẹ́ tí a mú ṣẹ dùn mọ́ ọkàn ṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi.

[20] Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára.

[21] Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo.

[22] Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo.

[23] Ilẹ̀ ẹ tálákà le è mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìre oko wá ṣùgbọ́n àìṣòdodo gbá gbogbo rẹ̀ lọ.

[24] Ẹni tí ó fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóò máa bá a wí.

[25] Olódodo jẹ́wọ́ títí ó fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ikùn ènìyàn búburú.

Ìwé Òwe — Chapters