[1] Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ẹ̀kọ́ fẹ́ ìmọ̀, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìgbọ́n.
[2] Ènìyàn rere gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa ṣùgbọ́n ènìyàn ètè búburú ni yóò dá lẹ́bi.
[3] A kò lè fi ẹsẹ̀ ènìyàn múlẹ̀ nípa ìwà búburú ṣùgbọ́n a kò le è fa olódodo tu.
[4] Aya oníwà rere ni adé ọkọ rẹ̀ ṣùgbọ́n aya adójútini dàbí inú egungun rẹ̀ jẹrà.
[5] Èrò àwọn olódodo tọ́, ṣùgbọ́n ìgbìmọ̀ ènìyàn búburú jẹ́ ẹ̀tàn.
[6] Ọ̀rọ̀ ènìyàn búburú lúgọ de ẹ̀jẹ̀ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn olódodo gbà wọ́n là.
[7] A ṣí àwọn ènìyàn búburú ní ìdí, wọn kò sì sí mọ́; ṣùgbọ́n ilé olódodo dúró ṣinṣin.
[8] A ń yín ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ọgbọ́n rẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ọlọ́pọlọ wúruwùru ni a kẹ́gàn.
[9] Ó sàn kí a má jẹ́ ènìyàn pàtàkì kí a sì ní ìránṣẹ́ ju kí a díbọ́n pé a jẹ́ ẹni pàtàkì láìní oúnjẹ.
[10] Olódodo ènìyàn ń ṣe aájò ohun tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ nílò, ṣùgbọ́n ìyọ́nú àwọn ènìyàn búburú, ìkà ni.
[11] Ẹni tí ó bá dá oko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásán làsàn kò gbọ́n.
[12] Ènìyàn búburú ń fẹ́ ìkógun àwọn ènìyàn ìkà ṣùgbọ́n gbòǹgbò olódodo ń gbilẹ̀.
[13] A mú ènìyàn búburú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n olódodo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdààmú.
[14] Láti inú èso rẹ̀, ènìyàn kún fún onírúurú ohun rere bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ti ń pín in lérè dájúdájú.
[15] Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn.
[16] Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ.
[17] Ẹni tí ó jẹ́ ajẹ́rìí òtítọ́ jẹ́rìí ohun tí ojú rẹ̀ rí ṣùgbọ́n ajẹ́rìí èké máa ń parọ́.
[18] Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń mú ìwòsàn wá.
[19] Ètè tí ń ṣọ òtítọ́ yóò wà láéláé ṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́.
[20] Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tí ń pète búburú ṣùgbọ́n ayọ̀ wà fún àwọn tí ń mú kí àlàáfíà gbilẹ̀.
[21] Ibi kì í ṣubú lu olódodo rárá ṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn.
[22] Olúwa kórìíra ètè tí ń parọ́ ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́.
[23] Ènìyàn olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde.
[24] Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jẹ ọba ṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí ẹrú ṣíṣe.
[25] Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀.
[26] Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́ ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn ṣìnà.
[27] Ọ̀lẹ ènìyàn kò sun ẹran tí ó pa lóko ọdẹ ṣùgbọ́n ẹni tí kì í ṣe ọ̀lẹ máa ń díwọ̀n ohun ìní rẹ̀.
[28] Ní ọ̀nà àwọn olódodo ni ìyè wà ní ọ̀nà náà ni àìkú wà.