[1] Ènìyàn tí kò ba ni rẹ́ a máa lépa ìmọ̀ ara rẹ̀; ó kọjú ìjà sí gbogbo ìdájọ́ òdodo.
[2] Aláìgbọ́n kò rí inú dídùn sí òye ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí sísọ èrò tirẹ̀.
[3] Nígbà ti ènìyàn búburú dé ni ẹ̀gàn dé, nígbà ti ẹ̀gàn dé ni ìtìjú dé.
[4] Ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn jẹ́ omi jíjìn, ṣùgbọ́n orísun ọgbọ́n jẹ́ odò tí ń sàn.
[5] Kò dára kí ènìyàn ṣe ojúsàájú fún ènìyàn búburú tàbí kí a fi ìdájọ́ òdodo du aláìṣẹ̀.
[6] Ètè aláìgbọ́n dá ìjà sílẹ̀ ẹnu rẹ̀ sì ń ṣokùnfà ẹgba.
[7] Ẹnu aláìgbọ́n ni ó ba tirẹ̀ jẹ́, ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹ̀kùn fún ọkàn rẹ̀.
[8] Ọ̀rọ̀ olófòófó dàbí oúnjẹ àdídùn; wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.
[9] Ẹni tí kò ṣe déédé nínú iṣẹ́ rẹ̀ arákùnrin ló jẹ́ fún apanirun.
[10] Orúkọ Olúwa, ilé ìṣọ́ agbára ni; olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà.
[11] Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn; wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni.
[12] Ṣáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéraga, ṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá.
[13] Ẹni tí ó ń fèsì kí ó tó gbọ́, èyí ni ìwà òmùgọ̀ àti ìtìjú rẹ̀.
[14] Ọkàn ènìyàn a máa gbé e ró nígbà àìsàn, ṣùgbọ́n ta ni ó le forí ti ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì.
[15] Ọkàn olóye ní i gba ìmọ̀; etí ọlọ́gbọ́n ní í ṣe àwárí rẹ̀.
[16] Ẹ̀bùn máa ń ṣí ọ̀nà fún ẹni tí ń fún ni lẹ́bùn a sì mú un wọlé sí ọ̀dọ̀ àwọn olókìkí.
[17] Ẹni tí ó kọ́kọ́ rọjọ́ máa ń dàbí i pé ó jàre, títí ẹlòmíràn yóò fi bọ́ síwájú kí ó sì tú àṣírí gbogbo.
[18] Ìbò dídì máa ń parí ìjà a sì mú kí àwọn alátakò méjì jìnnà sí ara wọn.
[19] Arákùnrin tí a ṣẹ̀ sí ṣòro yípadà ju ìlú olódi lọ, ìjà wọ sì dàbí ọ̀pá ìdábùú ààfin.
[20] Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ikùn ènìyàn a yó; láti inú ìkórè ẹnu rẹ̀ ni ó ti jẹ yó.
[21] Ikú àti ìyè ń bẹ nípa ahọ́n wọn, àwọn tí ó sì fẹ́ràn rẹ̀ yóò jẹ ẹ́.
[22] Ẹni tí ó rí aya fẹ́, rí ohun rere, o sì gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa.
[23] Tálákà ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú, ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ a dáhùn pẹ̀lú ìkanra.
[24] Ènìyàn tí ó ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ le è parun, ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ó súnmọ́ ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin.