Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 3:30

[1] Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi. Ṣùgbọ́n pa òfin mi mọ́ sí ọkàn rẹ.

[2] Nítorí ọjọ́ gígùn, ẹ̀mí gígùn, àti àlàáfíà, ni wọn yóò fi kùn un fún ọ.

[3] Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí wàláà àyà rẹ.

[4] Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojúrere àti orúkọ rere ní ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn.

[5] Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ.

[6] Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ òun yóò sì máa tọ́ ipa ọ̀nà rẹ.

[7] Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ bẹ̀rù Olúwa kí o sì kórìíra ibi.

[8] Èyí yóò mú ìlera fún ara rẹ àti okun fún àwọn egungun rẹ.

[9] Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún Olúwa, pẹ̀lú àkọ́so oko rẹ,

[10] nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnya àgbá rẹ yóò kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún wáìnì tuntun.

[11] Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olúwa má sì ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí,

[12] nítorí Olúwa a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wí bí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí.

[13] Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀, ẹni tí ó tún ní òye sí i,

[14] nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.

[15] Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ; kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.

[16] Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.

[17] Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura, òpópónà rẹ sì jẹ́ ti àlàáfíà.

[18] Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á; àwọn tí ó bá sì dìímú yóò rí ìbùkún gbà.

[19] Nípa ọgbọ́n, Olúwa fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn;

[20] nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní yà, àwọsánmọ̀ sì ń sẹ ìrì.

[21] Ọmọ mi, pa ọgbọ́n tí ó yè kooro àti ìmòye mọ́, má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn.

[22] Wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ, àti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ.

[23] Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìléwu, ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀.

[24] Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rù, nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò jẹ́ oorun ayọ̀.

[25] Má ṣe bẹ̀rù ìdààmú òjijì, tàbí ti ìparun tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn búburú.

[26] Nítorí Olúwa yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ, kì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté.

[27] Má ṣe fa ọwọ́ ìre sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ṣe tìrẹ, nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan.

[28] Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé, “Padà wá nígbà tó ṣe díẹ̀; èmi yóò fi fún ọ ní ọ̀la,” nígbà tí o ní i pẹ̀lú rẹ nísinsin yìí.

[29] Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ, ti o gbé nítòsí rẹ, tí ó sì fọkàn tán ọ.

[30] Má ṣe fẹ̀sùn kan ènìyàn láìnídìí, nígbà tí kò ṣe ọ́ ní ibi kankan rárá.

[31] Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgan tàbí kí o yàn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀.

[32] Nítorí Olúwa kórìíra ènìyàn aláyídáyidà ṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin.

[33] Ègún Olúwa ń bẹ lórí ilé ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ó bùkún fún ilé olódodo.

[34] Ó fi àwọn ẹlẹ́yà ṣe yẹ̀yẹ́, ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀.

[35] Ọlọ́gbọ́n jogún iyì, ṣùgbọ́n àwọn aṣiwèrè ni yóò ru ìtìjú wọn.

Ìwé Òwe — Chapters