Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 2:49

[1] Tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ mi, sí ẹ̀kọ́ baba; fetísílẹ̀ kí o sì ní òye sí i.

[2] Mo fún ọ ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, nítorí náà, má ṣe kọ ẹ̀kọ́ mi sílẹ̀.

[3] Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ní ilé baba à mí, mo jẹ́ èwe, tí mo sì jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi.

[4] Ó kọ́ mi ó sì wí pé, “Jẹ́ kí àyà rẹ kí ó gba ọ̀rọ̀ mi dúró, pa òfin mi mọ́, kí ìwọ kí ó sì yè.

[5] Gba ọgbọ́n, gba òye, má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹsẹ̀ kúrò nínú rẹ̀.

[6] Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́, fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojútó ọ.

[7] Ọgbọ́n ni ó ga jù; nítorí náà gba ọgbọ́n. Bí ó tilẹ̀ ná gbogbo ohun tí o ní, gba òye.

[8] Gbé e ga, yóò sì gbé ọ ga dìrọ̀ mọ́ ọn, yóò sì bu iyì fún ọ.

[9] Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹ yóò sì fi adé ẹlẹ́wà fún ọ.”

[10] Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ, ọjọ́ ayé è rẹ yóò sì gùn.

[11] Mo tọ́ ọ ṣọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́n mo sì mú ọ lọ ní ọ̀nà ti tààrà.

[12] Nígbà tí o rìn, ìgbésẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́ nígbà tí o bá sáré, ìwọ kì yóò kọsẹ̀.

[13] Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ; tọ́jú u rẹ̀ dáradára nítorí òun ni ìyè rẹ.

[14] Má ṣe gbé ẹsẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú tàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.

[15] Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀; yàgò fún un kí o sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ.

[16] Nítorí wọn kò le sùn àyàfi tí wọ́n bá ṣe ibi, wọn kò ní tòògbé àyàfi tí wọ́n bá gbé ẹlòmíràn ṣubú.

[17] Wọ́n ń jẹ oúnjẹ ìwà búburú wọ́n sì ń mu wáìnì ìwà ìkà.

[18] Ipa ọ̀nà olódodo dàbí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn tí ń tànmọ́lẹ̀ sí i títí ọjọ́ fi kanrí

[19] ṣùgbọ́n ọ̀nà ènìyàn búburú dàbí òkùnkùn biribiri; wọn kò mọ ohun tí ó ń mú wọn kọsẹ̀.

[20] Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ; fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi.

[21] Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójú pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ,

[22] nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó rí wọn àti ìlera fún gbogbo ara ènìyàn.

[23] Ju gbogbo nǹkan tókù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́, nítorí òun ni orísun ìyè.

[24] Mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ; sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ.

[25] Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo iwájú, jẹ́ kí ìwo ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sá á.

[26] Kíyèsi ìrìn ẹsẹ̀ rẹ sì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan.

[27] Má ṣe yà sọ́tùn ún tàbí sósì; pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú ibi.

Ìwé Òwe — Chapters