[1] Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padà ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókè.
[2] Ahọ́n ọlọ́gbọ́n a máa gbé ìmọ̀ jáde ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń tú ọ̀rọ̀ ọ òmùgọ̀ jáde.
[3] Ojú Olúwa wà níbi gbogbo, Ó ń wo àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.
[4] Ahọ́n tí ń mú ìtura wá jẹ́ igi ìyè ṣùgbọ́n ahọ́n ẹ̀tàn ń pa ẹ̀mí run.
[5] Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọ́gbọ́n.
[6] Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra, ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn.
[7] Ètè olódodo ń tan ìmọ̀ kalẹ̀; ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún ọkàn aláìgbọ́n.
[8] Olúwa kórìíra ìrúbọ àwọn ènìyàn búburú ṣùgbọ́n àdúrà olódodo tẹ́ ẹ lọ́rùn.
[9] Olúwa kórìíra ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ó fẹ́ràn àwọn tí ń lépa òdodo.
[10] Ẹni tí ó kúrò lójú ọ̀nà yóò rí ìbáwí gan an, ẹni tí ó kórìíra ìbáwí yóò kú.
[11] Ikú àti ìparun ṣí sílẹ̀ níwájú Olúwa, mélòó mélòó ní nínú ọkàn àwọn ènìyàn.
[12] Ẹlẹ́gàn kò fẹ́ ẹni tí ń ba wí: kò ní gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ọlọ́gbọ́n.
[13] Inú dídùn máa ń mú kí ojú túká ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ọkàn máa ń pa ẹ̀mí run.
[14] Ọkàn olóye ń wá ìmọ̀ ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń fẹ́ ìwà òmùgọ̀ bí ẹní jẹun.
[15] Gbogbo ọjọ́ àwọn olùpọ́njú jẹ́ ibi, ṣùgbọ́n onínúdídùn ń jẹ àlàáfíà ní ìgbà gbogbo.
[16] Ó sàn kí ó má pọ̀, kí ìbẹ̀rù Olúwa sì wà ju ọrọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú ìyọnu.
[17] Oúnjẹ ewébẹ̀ níbi tí ìfẹ́ wà sàn ju àbọ́pa màlúù tòun ti ìríra.
[18] Ènìyàn onínú ríru dá ìjà sílẹ̀ ṣùgbọ́n onísùúrù paná ìjà.
[19] Ọ̀nà ọ̀lẹ ni ẹ̀gún dí, ṣùgbọ́n ọ̀nà olódodo já geerege ni.
[20] Ọlọ́gbọ́n ọmọ mú inú baba rẹ̀ dùn, ṣùgbọ́n aṣiwèrè ènìyàn kẹ́gàn ìyá rẹ̀.
[21] Inú ènìyàn aláìlóye a máa dùn sí ìwà òmùgọ̀; ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa rin ọ̀nà tààrà.
[22] Ìgbèrò a máa dasán níbi tí kò sí ìmọ̀ràn; ṣùgbọ́n a máa yege níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn wà.
[23] Inú ènìyàn a máa dùn nígbà tí ó bá fèsì tó yẹ ọ̀rọ̀ tí ó bá sì wá lásìkò tó yẹ dára púpọ̀!
[24] Ọ̀nà ìyè ń lọ sókè fún ọlọ́gbọ́n láti sọ kí ó má bá à sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú.
[25] Olúwa fa ilé onígbèéraga ya lulẹ̀, ṣùgbọ́n ó pa ààlà opó onírẹ̀lẹ̀ mọ́ láìyẹ̀.
[26] Olúwa kórìíra èrò ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n mímọ́ ni ọ̀rọ̀ ẹni pípé.
[27] Ọ̀kánjúwà ènìyàn mú ìyọnu bá ilé rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò yè.
[28] Ọkàn olódodo ń wọn ìdáhùn wò ṣùgbọ́n ẹnu ènìyàn búburú ń tú ibi jáde.
[29] Olúwa jìnnà sí ènìyàn búburú ṣùgbọ́n ó ń gbọ́ àdúrà olódodo.
[30] Ojú tó túká máa ń mú ayọ̀ wá fún ọkàn, ìròyìn ayọ̀ sì ń mú ìlera wá sínú egungun.
[31] Ẹni tí ó fetí sí ìbáwí tí ń fún ni ní ìyè, yóò wà ní àpéjọpọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n.
[32] Ẹni tí ó kọ̀ ìbáwí kẹ́gàn ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí yóò ní ìmọ̀ sí i.
[33] Ìbẹ̀rù Olúwa kọ́ ènìyàn ní ọgbọ́n, ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ọlá.