Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 3:21

[1] Wọ̀nyí ni àwọn òwe mìíràn tí Solomoni pa, tí àwọn ọkùnrin Hesekiah ọba Juda dà kọ.

[2] Ògo Ọlọ́run ní láti fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́; láti rí ìdí ọ̀rọ̀ kan ni ògo àwọn ọba.

[3] Bí ọ̀run ṣe ga tó tí ayé sì jì bẹ́ẹ̀ ni ó ṣòro láti mọ èrò ọkàn ọba.

[4] Mú ìdàrọ́ kúrò lára fàdákà ohun èlò yóò sì jáde fún alágbẹ̀dẹ fàdákà.

[5] Mú ènìyàn búburú kúrò níwájú ọba a ó sì fìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ nípasẹ̀ òdodo.

[6] Má ṣe gbé ara rẹ ga níwájú ọba, má sì ṣe jìjàdù ààyè láàrín àwọn ènìyàn pàtàkì,

[7] ó sàn kí ó wí fún ọ pé, “Gòkè wá síyìn-ín,” ju wí pé kí ó dójútì ọ́ níwájú ènìyàn pàtàkì.

[8] Ohun tí o ti fi ojú ara rẹ rí má ṣe kánjú gbé e lọ sílé ẹjọ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe ní ìgbẹ̀yìn bí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́?

[9] Bí o bá ń ṣe àwíjàre rẹ níwájú aládùúgbò rẹ, má ṣe tú àṣírí tí ẹlòmíràn ní lọ́dọ̀ rẹ,

[10] àìṣe bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ le dójútì ọ́ orúkọ búburú tí ìwọ bá sì gba kì yóò tán láéláé.

[11] Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó yẹ ó dàbí èso wúrà nínú àpẹẹrẹ fàdákà.

[12] Bí i yẹtí wúrà tàbí ohun ọ̀ṣọ́ ti wúrà dáradára ni ìbáwí ọlọ́gbọ́n fún etí tí ó bá fetísílẹ̀.

[13] Bí títutù òjò yìnyín ní àsìkò ìkórè ni ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olóòtítọ́ sí àwọn tí ó rán an ó ń tu ọ̀gá rẹ̀ nínú.

[14] Bí ojú ṣíṣú àti afẹ́fẹ́ láìsí òjò ni ènìyàn tí ń yangàn nípa ẹ̀bùn tí kò fún ni.

[15] Nípa sùúrù a lè yí ọba lọ́kàn padà ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ rírọ̀ sí egungun.

[16] Bí ìwọ bá rí oyin, jẹ ẹ́ ní ìwọ̀nba bí o bá jẹ ẹ́ jù, ìwọ yóò sì bì í.

[17] Má ṣe máa lọ sí ilé aládùúgbò rẹ nígbà gbogbo tàbí kí ó máa lọ síbẹ̀ lálọ jù, yóò sì kórìíra rẹ.

[18] Bí ọ̀pá, idà tàbí ọ̀kọ̀ tí ó mú ni ènìyàn tí ó jẹ́rìí èké lòdì sí aládùúgbò rẹ̀.

[19] Bí eyín tí ó bàjẹ́ tàbí ẹsẹ̀ tí ó rọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé lórí aláìṣòótọ́ ní àsìkò ìdààmú.

[20] Bí ẹni tí ó bọ́ra kalẹ̀ ní ọjọ́ tí òtútù mú, tàbí, bí ọtí kíkan tí a dà sí ojú ọgbẹ́, ní ẹni tí ń kọ orin fún ẹni tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́.

[21] Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mú.

[22] Nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóò wa ẹ̀yín iná lé e lórí Olúwa yóò sì san ọ ní ẹ̀san rẹ̀ fún ọ.

[23] Bí afẹ́fẹ́ gúúsù ti í mú òjò wá, bí ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ṣe ń mú ojú ìbínú wá.

[24] Ó sàn láti gbé ní ibi igun kan lórí òrùlé ju láti bá aya oníjà gbé ilé pọ̀.

[25] Bí omi tútù sí ọkàn tí ń ṣe àárẹ̀ ni ìròyìn ayọ̀ láti ọ̀nà jíjìn.

[26] Bí ìsun tí ó di àbàtà tàbí kànga tí omi rẹ̀ bàjẹ́ ni olódodo tí ó fi ààyè gba ènìyàn búburú.

[27] Kò dára láti jẹ oyin àjẹjù, bẹ́ẹ̀ ni kò pọ́n ni lé láti máa wá ọlá fún ara ẹni.

[28] Bí ìlú tí odi rẹ̀ ti wó lulẹ̀ ni ènìyàn tí kò le kó ara rẹ̀ ní ìjánu.

Ìwé Òwe — Chapters