[1] Benjamini jẹ́ baba: Bela àkọ́bí rẹ̀, Aṣbeli ọmọkùnrin ni ẹ̀ẹ̀kejì, Ahara ẹ̀ẹ̀kẹ́ta,
[2] Noha ẹ̀ẹ̀kẹrin àti Rafa ẹ̀karùnún.
[3] Àwọn ọmọ Bela ni, Adari, Gera, Abihudi,
[4] Abiṣua, Naamani, Ahoa,
[5] Gera, Ṣefufani àti Huramu.
[6] Wọ̀nyí ni àwọn ìran ọmọ Ehudu, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé tí ó ń gbé ní Geba tí a sì lé kúrò lọ sí Manahati:
[7] Naamani Ahijah àti Gera, tí ó lé wọn kúrò ní ìlú, àti tí ó sì jẹ́ baba Ussa àti Ahihudu.
[8] A bí àwọn ọmọkùnrin fún Ṣaharaimu ní Moabu lẹ́yìn tí ó ti kọ àwọn ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, Huṣimu àti Baara.
[9] Nípasẹ̀ ìyàwó rẹ̀ Hodeṣi ó ní Jobabu Sibia, Meṣa, Malkamu,
[10] Jeusi, Sakia àti Mirma. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, olórí àwọn ìdílé.
[11] Nípasẹ̀ Huṣimu ó ní Abitubu àti Elipali.
[12] Àwọn ọmọ Elipali: Eberi, Miṣamu, Ṣemedu (ẹni tí ó kọ́ Ono àti Lodi pẹ̀lú àwọn ìletò àyíká rẹ̀.)
[13] Pẹ̀lú Beriah àti Ṣema, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé ti àwọn tí ó ń gbé ní Aijaloni àti àwọn tí ó lé àwọn olùgbé Gati kúrò.
[14] Ahio, Ṣasaki, Jeremoti,
[15] Sebadiah, Aradi, Ederi
[16] Mikaeli, Iṣifa àti Joha jẹ́ àwọn ọmọ Beriah.
[17] Sebadiah, Meṣullamu, Hiski, Heberi
[18] Iṣimerai, Isiliahi àti Jobabu jẹ́ àwọn ọmọ Elipali.
[19] Jakimu, Sikri, Sabdi,
[20] Elienai, Siletai, Elieli,
[21] Adaiah, Beraiah àti Ṣimrati jẹ́ àwọn ọmọ, Ṣimei.
[22] Iṣipani Eberi, Elieli,
[23] Abdoni, Sikri, Hanani,
[24] Hananiah, Elamu, Anitotijah,
[25] Ifediah àti Penueli jẹ́ àwọn ọmọ Ṣasaki.
[26] Ṣamṣerai, Ṣeharaiah, Ataliah
[27] Jareṣiah, Elijah àti Sikri jẹ́ àwọn ọmọ Jerohamu.
[28] Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn ìdílé, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìran wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jerusalẹmu.
[29] Jeieli, baba Gibeoni ń gbé ní Gibeoni. Ìyàwó o rẹ̀ a má jẹ́ Maaka,
[30] àkọ́bí rẹ̀ a sì máa jẹ́ Abdoni wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Suri, Kiṣi, Baali, Neri, Nadabu,
[31] Gedori Ahio, Sekeri
[32] pẹ̀lú Mikiloti, tí ó jẹ́ baba Ṣimea. Wọ́n ń gbé ní ẹ̀bá ìbátan wọn ní Jerusalẹmu.
[33] Neri jẹ́ baba Kiṣi, Kiṣi baba Saulu àti Saulu baba Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu àti Eṣi-Baali.
[34] Ọmọ Jonatani: Meribu-Baali tí ó jẹ́ baba Mika.
[35] Àwọn ọmọ Mika: Pitoni, Meleki, Tarea, àti Ahasi.
[36] Ahasi jẹ́ baba a Jeheada, Jeheada jẹ́ baba a Alemeti, Asmafeti àti Simri, Simri sì jẹ́ baba Mosa.
[37] Mosa jẹ́ baba Binea; Rafa sì jẹ́ ọmọ rẹ̀, Eleasa ọmọ rẹ̀ àti Aseli ọmọ rẹ̀.
[38] Aseli ní ọmọ mẹ́fà pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn: Asrikamu, Bokeru, Iṣmaeli, Ṣeariah, Obadiah àti Hanani. Gbogbo wọ̀nyí ni ọmọ Aseli.
[39] Àwọn ọmọ arákùnrin rẹ̀ Eseki: Ulamu àkọ́bí rẹ̀, Jeuṣi ọmọkùnrin ẹ̀ẹ̀kejì àti Elifeleti ẹ̀ẹ̀kẹ́ta.
[40] Àwọn ọmọ Ulamu jẹ́ ògboyà jagunjagun tí ó lè gbá orin mú. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin àti ọmọ ọmọkùnrin áàdọ́jọ ní gbogbo rẹ̀. Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ìran ọmọ Benjamini.