[1] Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, wá sínú àgọ́ ti Dafidi ti pèsè fún un, wọ́n sì gbé ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀ kalẹ̀ níwájú Ọlọ́run.
[2] Lẹ́yìn tí Dafidi parí ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, ó bùkún àwọn ènìyàn ní orúkọ Olúwa.
[3] Nígbà náà ó fún olúkúlùkù ọkùnrin àti obìnrin ọmọ Israẹli ní ìṣù àkàrà kan, àkàrà dídùn ti àkókò kan àti àkàrà dídùn ti èso àjàrà kan.
[4] Ó yan díẹ̀ lára àwọn ará Lefi láti máa jọ́sìn níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, àti láti ṣe ìrántí àti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa, Ọlọ́run Israẹli.
[5] Asafu ni olóyè, àtẹ̀lé rẹ ni Sekariah, Jehieli, Ṣemiramotu, Asieli, Mattitiah, Eliabu, Benaiah, Obedi-Edomu àti Jeieli, àwọn ni yóò lu ohun èlò orin olókùn àti dùùrù haapu. Asafu ni yóò lu símbálì kíkan.
[6] Àti Benaiah àti Jahasieli àwọn àlùfáà ni yóò fọn ìpè nígbà gbogbo níwájú àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú ti Ọlọ́run.
[7] Ní ọjọ́ náà Dafidi kọ́kọ́ fi lé Asafu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ orin Dafidi ti ọpẹ́ sí Olúwa.
[8] Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ẹ pe orúkọ rẹ̀, ẹ fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nínú àwọn ènìyàn fún ohun tí ó ṣe
[9] Ẹ kọrin sí i, ẹ kọrin ìyìn, sí i, ẹ sọ ti gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.
[10] Ìyìn nínú orúkọ rẹ̀ mímọ́; jẹ kí ọkàn àwọn tí ó yin Olúwa kí ó yọ̀.
[11] Ẹ wá Olúwa àti agbára rẹ̀; e wá ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.
[12] Rántí àwọn ìyanu tí Ó ti ṣe, iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àti ìdájọ́ tí Ó ti sọ.
[13] A! ẹ̀yin ìran ọmọ Israẹli ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọmọ Jakọbu, ẹ̀yin tí ó ti yàn.
[14] Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa; ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.
[15] Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé, ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran,
[16] májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu, ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki.
[17] Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé:
[18] “Sí ọ, ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ Kenaani. Gẹ́gẹ́ bí ààyè tí ìwọ yóò jogún.”
[19] Nígbà tí wọn kéré ní iye, wọ́n kéré gidigidi, wọ́n sì jẹ́ àlejò níbẹ̀,
[20] wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè láti ìjọba kan sí èkejì.
[21] Kò gba ọkùnrin kankan láyè láti pọ́n wọn lójú; nítorí tiwọn, ó bá àwọn ọba wí.
[22] “Má ṣe fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi; má ṣe pa àwọn wòlíì mi lára.”
[23] Kọrin sí Olúwa gbogbo ayé; ẹ máa fi ìgbàlà rẹ̀ hàn láti ọjọ́ dé ọjọ́.
[24] Kéde ògo à rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun ìyàlẹ́nu tí ó ṣe láàrín gbogbo ènìyàn.
[25] Nítorí títóbi ni Olúwa òun sì ni ìyìn yẹ jùlọ; òun ni kí a bẹ̀rù ju gbogbo àwọn Ọlọ́run lọ.
[26] Nítorí gbogbo àwọn ọlọ́run orílẹ̀-èdè jẹ́ àwọn òrìṣà, ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run.
[27] Dídán àti ọláńlá ni ó wà níwájú rẹ̀; agbára àti ayọ̀ ni ó wà ní ibi ibùgbé rẹ̀.
[28] Fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ fi ògo àti ipá fún Olúwa.
[29] Fún Olúwa ní ìyìn nítorí orúkọ rẹ̀; gbé ọrẹ kí ẹ sì wá síwájú rẹ̀. Sìn Olúwa nínú inú dídùn ìwà mímọ́ rẹ̀.
[30] Wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé! Ayé sì fi ìdí múlẹ̀; a kò sì le è ṣí i.
[31] Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn; lẹ́ kí wọn kí ó sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, pé “Olúwa jẹ ọba!”
[32] Jẹ́ kí ọ̀run kí ó tún dún padà, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀; Jẹ́ kí àwọn pápá kí ó hó fún ayọ̀, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀!
[33] Nígbà náà ni igi igbó yóò kọrin, wọn yóò kọrin fún ayọ̀ níwájú Olúwa, nítorí tí ó wá láti ṣèdájọ́ ayé.
[34] Fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára; ìfẹ́ ẹ rẹ̀ dúró títí láé.
[35] Ké lóhùn rara, “Gbà wá, Ọlọ́run olùgbàlà a wa; kó wa jọ kí o sì gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, kí àwa kí ó lè fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ, kí àwa kí ó lè yọ̀ nínú ìyìn rẹ̀.”
[36] Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, láé àti láéláé. Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn ènìyàn wí pé, “Àmín,” wọ́n “Yin Olúwa.”
[37] Dafidi fi Asafu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa láti jíṣẹ́ níbẹ̀ déédé, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe gbà.
[38] Ó fi Obedi-Edomu àti méjìdínláàádọ́rin ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú wọn. Obedi-Edomu mọ Jedutuni, àti Hosa pẹ̀lú jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà.
[39] Dafidi fi Sadoku àlùfáà àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níwájú Àgọ́ Olúwa ní ibi gíga ní Gibeoni.
[40] Láti gbé pẹpẹ ẹbọ sísun déédé, àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ sínú òfin Olúwa, tí ó ti fún Israẹli.
[41] Pẹ̀lú wọn ni Hemani àti Jedutuni àti ìyókù tí a mú àti yàn nípasẹ̀ orúkọ láti fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró títí láéláé
[42] Hemani àti Jedutuni ni wọ́n dúró fún fífọn ìpè àti Kimbali àti fún lílo ohun èlò yòókù fún orin Ọlọ́run. Àwọn ọmọ Jedutuni wà ní ipò dídúró ní ẹnu-ọ̀nà.
[43] Nígbà náà gbogbo àwọn ènìyàn kúrò, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀: Dafidi yípadà láti súre fún ìdílé rẹ̀.