[1] Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli. Reubeni, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Sebuluni,
[2] Dani, Josẹfu, Benjamini; Naftali, Gadi: àti Aṣeri.
[3] Àwọn ọmọ Juda: Eri, Onani àti Ṣela, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kenaani, ọmọbìnrin Ṣua. Eri àkọ́bí Juda, ó sì burú ní ojú Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì pa á.
[4] Tamari, aya ọmọbìnrin Juda, ó sì bí Peresi àti Sera sì ní ọmọ márùn-ún ní àpapọ̀.
[5] Àwọn ọmọ Peresi: Hesroni àti Hamulu.
[6] Àwọn ọmọ Sera: Simri, Etani, Hemani, Kalkoli àti Dara, gbogbo wọn jẹ́ márùn-ún.
[7] Àwọn ọmọ Karmi: Akani, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Israẹli nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀.
[8] Àwọn ọmọ Etani: Asariah.
[9] Àwọn ọmọ tí a bí fún Hesroni ni: Jerahmeeli, Ramu àti Kalebu.
[10] Ramu sì ni baba Amminadabu, àti Amminadabu baba Nahiṣoni olórí àwọn ènìyàn Juda.
[11] Nahiṣoni sì ni baba Salmoni, Salmoni ni baba Boasi,
[12] Boasi baba Obedi àti Obedi baba Jese.
[13] Jese sì ni baba Eliabu àkọ́bí rẹ̀; ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kejì sì ni Abinadabu, ẹlẹ́ẹ̀kẹta ni Ṣimea,
[14] ẹlẹ́ẹ̀kẹrin Netaneli, ẹlẹ́ẹ̀karùnún Raddai,
[15] ẹlẹ́ẹ̀kẹfà Osemu àti ẹlẹ́ẹ̀keje Dafidi.
[16] Àwọn arábìnrin wọn ni Seruiah àti Abigaili. Àwọn ọmọ mẹ́ta Seruiah ni Abiṣai, Joabu àti Asaheli.
[17] Abigaili ni ìyá Amasa, ẹni tí baba rẹ̀ sì jẹ́ Jeteri ará Iṣmaeli.
[18] Kalebu ọmọ Hesroni ní ọmọ láti ọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ̀ Asuba (láti ọ̀dọ̀ Jerioti). Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ rẹ̀: Jeṣeri, Ṣobabu àti Ardoni.
[19] Nígbà tí Asuba sì kú, Kalebu sì fẹ́ Efrata ní aya, ẹni tí ó bí Huri fún un.
[20] Huri ni baba Uri, Uri sì jẹ́ baba Besaleli.
[21] Nígbà tí ó yá, Hesroni sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin Makiri baba Gileadi (ó sì ti fẹ́ ní aya láti ìgbà tí ó ti wà ní ẹni ọgọ́ta ọdún) ó sì bí Segubu.
[22] Segubu sì jẹ́ baba Jairi, ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìlú mẹ́tàlélógún ní ilẹ̀ Gileadi.
[23] (Ṣùgbọ́n Geṣuri àti Aramu sì fi agbára gba Hafoti-Jairi, àti Kenati pẹ̀lú gbogbo agbègbè rẹ̀ tí wọn tẹ̀dó sí jẹ́ ọgọ́ta ìlú.) Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Makiri baba Gileadi.
[24] Lẹ́yìn tí Hesroni sì kú ni Kalebu Efrata, Abijah ìyàwó rẹ̀ ti Hesroni sì bí Aṣihuri baba Tekoa fún un.
[25] Ọmọ Jerahmeeli àkọ́bí Hesroni: Ramu ọmọ àkọ́bí rẹ̀ Buna, Oreni, Osemu àti Ahijah.
[26] Jerahmeeli ní ìyàwó mìíràn, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Atara; ó sì jẹ́ ìyá fún Onamu.
[27] Àwọn ọmọ Ramu àkọ́bí Jerahmeeli: Maasi, Jamini àti Ekeri.
[28] Àwọn ọmọ Onamu: Ṣammai àti Jada. Àwọn ọmọ Ṣammai: Nadabu àti Abiṣuri.
[29] Orúkọ ìyàwó Abiṣuri ni Abihaili ẹni tí ó bí Ahbani àti Molidi.
[30] Àwọn ọmọ Nadabu Seledi àti Appaimu. Seledi sì kú láìsí ọmọ.
[31] Àwọn ọmọ Appaimu: Iṣi, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Ṣeṣani. Ṣeṣani sì jẹ́ baba fún Ahlai.
[32] Àwọn ọmọ Jada, arákùnrin Ṣammai: Jeteri àti Jonatani. Jeteri sì kú láìní ọmọ.
[33] Àwọn ọmọ Jonatani: Peleti àti Sasa. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Jerahmeeli.
[34] Ṣeṣani kò sì ní ọmọkùnrin àwọn ọmọbìnrin nìkan ni ó ní. Ó sì ní ìránṣẹ́ ará Ejibiti tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jariha.
[35] Ṣeṣani sì fi ọmọ obìnrin rẹ̀ ní aya fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Jariha, ó sì bí ọmọ fún tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Attai.
[36] Attai sì jẹ́ baba fún Natani, Natani sì jẹ́ baba fún Sabadi,
[37] Sabadi ni baba Eflali, Eflali jẹ́ baba Obedi,
[38] Obedi sì ni baba Jehu, Jehu ni baba Asariah,
[39] Asariah sì ni baba Helesi, Helesi ni baba Eleasa,
[40] Eleasa ni baba Sismai, Sismai ni baba Ṣallumu,
[41] Ṣallumu sì ni baba Jekamiah, Jekamiah sì ni baba Eliṣama.
[42] Àwọn ọmọ Kalebu arákùnrin Jerahmeeli: Meṣa àkọ́bí rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Sifi, àti àwọn ọmọ rẹ̀ Meraṣa, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Hebroni.
[43] Àwọn ọmọ Hebroni: Kora, Tapua, Rekemu, àti Ṣema.
[44] Ṣema ni baba Rahamu, Rahamu sì jẹ́ baba fún Jorkeamu. Rekemu sì ni baba Ṣammai.
[45] Àwọn ọmọ Ṣammai ni Maoni, Maoni sì ni baba Beti-Suri.
[46] Efani obìnrin Kalebu sì ni ìyá Harani, Mosa àti Gasesi, Harani sì ni baba Gasesi.
[47] Àwọn ọmọ Jahdai: Regemu, Jotamu, Geṣani, Peleti, Efani àti Ṣaafu.
[48] Maaka obìnrin Kalebu sì ni ìyá Seberi àti Tirhana.
[49] Ó sì bí Ṣaafu baba Madmana, Ṣefa baba Makbena àti baba Gibeah, ọmọbìnrin Kalebu sì ni Aksa.
[50] Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Kalebu. Àwọn ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata: Ṣobali baba Kiriati-Jearimu.
[51] Salma baba Bẹtilẹhẹmu àti Harefu baba Beti-Gaderi.
[52] Àwọn ọmọ Ṣobali baba Kiriati-Jearimu ni: Haroe, ìdajì àwọn ará Manaheti.
[53] Àti ìdílé Kiriati-Jearimu: àti àwọn ara Itri, àti àwọn ará Puti, àti àwọn ará Ṣumati àti àwọn ará Miṣraiti: láti ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn ọmọ ará Sorati àti àwọn ará Eṣtaoli ti wá.
[54] Àwọn ọmọ Salma: Bẹtilẹhẹmu, àti àwọn ará Netofa, Atrotu Beti-Joabu, ìdajì àwọn ará Manahati, àti ará Sori,
[55] àti àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé, ẹni tí ń gbé ní Jabesi: àti àwọn ọmọ Tirati àti àwọn ará Ṣimeati àti àwọn ará Sukati. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ará Keni, ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Hamati, baba ilé Rekabu.