[1] Àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.
[2] Àwọn ọmọ Kohati: Amramu, Isari, Hebroni, àti Usieli.
[3] Àwọn ọmọ Amramu: Aaroni, Mose àti Miriamu. Àwọn ọmọkùnrin Aaroni: Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari.
[4] Eleasari jẹ́ baba Finehasi, Finehasi baba Abiṣua
[5] Abiṣua baba Bukki, Bukki baba Ussi,
[6] Ussi baba Serahiah, Serahiah baba Meraioti,
[7] Meraioti baba Amariah, Amariah baba Ahitubu
[8] Ahitubu baba Sadoku, Sadoku baba Ahimasi,
[9] Ahimasi baba Asariah, Asariah baba Johanani,
[10] Johanani baba Asariah. (Òhun ni ó sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà nínú ilé Olúwa tí Solomoni kọ́ sí Jerusalẹmu).
[11] Asariah baba Amariah Amariah baba Ahitubu
[12] Ahitubu baba Sadoku. Sadoku baba Ṣallumu,
[13] Ṣallumu baba Hilkiah, Hilkiah baba Asariah,
[14] Asariah baba Seraiah, pẹ̀lú Seraiah baba Josadaki.
[15] A kó Josadaki lẹ́rú nígbà tí Olúwa lé Juda àti Jerusalẹmu kúrò ní ìlú nípasẹ̀ Nebukadnessari.
[16] Àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.
[17] Wọ̀nyí ni àwọn orúkọ àwọn ọmọ Gerṣoni: Libni àti Ṣimei.
[18] Àwọn ọmọ Kohati: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.
[19] Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi. Wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ará Lefi tí a kọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí baba wọn.
[20] Ti Gerṣoni: Libni ọmọkùnrin rẹ̀, Jahati. Ọmọkùnrin rẹ̀, Simma ọmọkùnrin rẹ̀,
[21] Joah ọmọkùnrin rẹ̀, Iddo ọmọkùnrin rẹ̀, Sera ọmọkùnrin rẹ̀ àti Jeaterai ọmọkùnrin rẹ̀.
[22] Àwọn ìran ọmọ Kohati: Amminadabu ọmọkùnrin rẹ̀, Kora ọmọkùnrin rẹ̀, Asiri ọmọkùnrin rẹ̀.
[23] Elkana ọmọkùnrin rẹ̀, Ebiasafi ọmọkùnrin rẹ̀, Asiri ọmọkùnrin rẹ̀.
[24] Tahati ọmọkùnrin rẹ̀, Urieli ọmọkùnrin rẹ̀, Ussiah ọmọkùnrin rẹ̀ àti Saulu ọmọkùnrin rẹ̀.
[25] Àwọn ìran ọmọ Elkana: Amasai, Ahimoti
[26] Elkana ọmọ rẹ̀, Sofai ọmọ rẹ̀ Nahati ọmọ rẹ̀,
[27] Eliabu ọmọ rẹ̀, Jerohamu ọmọ rẹ̀, Elkana ọmọ rẹ̀ àti Samuẹli ọmọ rẹ̀.
[28] Àwọn ọmọ Samuẹli: Joẹli àkọ́bí àti Abijah ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kejì.
[29] Àwọn ìran ọmọ Merari: Mahili, Libni ọmọ rẹ̀. Ṣimei ọmọ rẹ̀, Ussa ọmọ rẹ̀.
[30] Ṣimea ọmọ rẹ̀, Haggiah ọmọ rẹ̀ àti Asaiah ọmọ rẹ̀.
[31] Èyí ní àwọn ọkùnrin Dafidi tí a fi sí ìdí orin nínú ilé Olúwa lẹ́yìn tí àpótí ẹ̀rí ti wá láti sinmi níbẹ̀.
[32] Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin níwájú àgọ́ ìpàdé títí tí Solomoni fi kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu. Wọ́n ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn.
[33] Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn. Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Kohati: Hemani olùkọrin, ọmọ Joẹli, ọmọ Samuẹli,
[34] ọmọ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elieli, ọmọ Toha,
[35] ọmọ Sufu, ọmọ Elkana, ọmọ Mahati, ọmọ Amasai,
[36] ọmọ Elkana, ọmọ Joẹli, ọmọ Asariah, ọmọ Sefaniah,
[37] ọmọ Tahati, ọmọ Asiri, ọmọ Ebiasafi, ọmọ Kora,
[38] ọmọ Isari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli;
[39] Hemani sì darapọ̀ mọ́ Asafu, ẹni tí o sìn ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀: Asafu ọmọ Berekiah, ọmọ Ṣimea,
[40] ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseiah, ọmọ Malkiah
[41] ọmọ Etini, ọmọ Sera, ọmọ Adaiah,
[42] ọmọ Etani, ọmọ Simma, ọmọ Ṣimei,
[43] ọmọ Jahati, ọmọ Gerṣoni, ọmọ Lefi;
[44] láti ìbákẹ́gbẹ́ wọn, àwọn ará Merari wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀: Etani ọmọ Kiṣi, ọmọ Abdi, ọmọ Malluki,
[45] ọmọ Haṣabiah, ọmọ Amasiah, ọmọ Hilkiah,
[46] ọmọ Amisi, ọmọ Bani, ọmọ Ṣemeri,
[47] ọmọ Mahili, ọmọ Muṣi, ọmọ Merari, ọmọ Lefi.
[48] Àwọn Lefi ẹgbẹ́ wọn ni wọn yan àwọn iṣẹ́ yòókù ti àgọ́ fún, èyí tí í ṣe ilé Ọlọ́run.
[49] Ṣùgbọ́n Aaroni àti àwọn ìran ọmọ rẹ̀ jẹ́ àwọn tí ó gbé ọrẹ kalẹ̀ lórí pẹpẹ ẹbọ sísun àti lórí pẹpẹ tùràrí ní ìbátan pẹ̀lú gbogbo ohun tí a ṣe ní Ibi Mímọ́ Jùlọ. Ṣíṣe ètùtù fún Israẹli, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti pàṣẹ.
[50] Wọ̀nyí ni àwọn ìránṣẹ́ Aaroni: Eleasari ọmọ rẹ̀, Finehasi ọmọ rẹ̀, Abiṣua ọmọ rẹ̀,
[51] Bukki ọmọ rẹ̀, Ussi ọmọ rẹ̀, Serahiah ọmọ rẹ̀,
[52] Meraioti ọmọ rẹ̀, Amariah ọmọ rẹ̀, Ahitubu ọmọ rẹ̀,
[53] Sadoku ọmọ rẹ̀ àti Ahimasi ọmọ rẹ̀.
[54] Wọ̀nyí ni ibùgbé wọn tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbègbè wọn (tí a fi lé àwọn ìran ọmọ Aaroni lọ́wọ́ tí ó wá láti ẹ̀yà Kohati, nítorí kèké alákọ́kọ́ jẹ́ tiwọn).
[55] A fún wọn ní Hebroni ní Juda pẹ̀lú àyíká pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀.
[56] Ṣùgbọ́n àwọn pápá àti ìletò tí ó yí ìlú ńlá náà ká ni a fi fún Kalebu ọmọ Jefunne.
[57] Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìran ọmọ Aaroni ni a fún ní Hebroni (ìlú ti ààbò), àti Libina, Jattiri, Eṣitemoa,
[58] Hileni, Debiri,
[59] Aṣani, Jutta àti Beti-Ṣemeṣi lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀.
[60] Àti láti inú ẹ̀yà Benjamini, a fún wọn ní Gibeoni, Geba, Alemeti àti Anatoti lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn. Àwọn ìlú wọ̀nyí, tí a pín láàrín àwọn ẹ̀yà Kohati jẹ́ mẹ́tàlá ní gbogbo rẹ̀.
[61] Ìyókù àwọn ìran ọmọ Kohati ní a pín ìlú mẹ́wàá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase.
[62] Àwọn ìran ọmọ Gerṣoni, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́tàlá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Isakari, Aṣeri àti Naftali, àti láti apá ẹ̀yà Manase tí ó wà ní Baṣani.
[63] Sebuluni àwọn ìran ọmọ Merari, ìdílé sí ìdílé, ní a pín ìlú méjìlá fún láti ẹ̀yà Reubeni, Gadi àti Sebuluni.
[64] Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli fún àwọn ará Lefi ní ìlú wọ̀nyí pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
[65] Láti ẹ̀yà Juda, Simeoni àti Benjamini ni a pín ìlú tí a ti dárúkọ wọn sẹ́yìn fún.
[66] Lára àwọn ìdílé Kohati ni a fún ní ìlú láti ẹ̀yà Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìlú agbègbè wọn.
[67] Ní òkè orílẹ̀-èdè Efraimu, a fún wọn ní Ṣekemu (ìlú ńlá ti ààbò), àti Geseri
[68] Jokimeamu, Beti-Horoni.
[69] Aijaloni àti Gati-Rimoni lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
[70] Pẹ̀lú láti apá ààbọ̀ ẹ̀yà Manase àwọn ọmọ Israẹli fún Aneri àti Bileamu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn, fún ìyókù àwọn ìdílé Kohati.
[71] Àwọn ará Gerṣoni gbà nǹkan wọ̀nyí. Láti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Manase wọ́n gba Golani ní Baṣani àti pẹ̀lú Aṣtarotu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù wọn.
[72] Láti ẹ̀yà Isakari wọ́n gba Kedeṣi, Daberati
[73] Ramoti àti Anenu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
[74] Láti ẹ̀yà Aṣeri wọ́n gba Maṣali, Abdoni,
[75] Hukoki àti Rehobu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
[76] Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Naftali wọ́n gba Kedeṣi ní Galili, Hammoni àti Kiriataimu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
[77] Àwọn ará Merari (ìyókù àwọn ará Lefi) gbà nǹkan wọ̀nyí. Láti ẹ̀yà Sebuluni wọ́n gba Jokneamu, Karta, Rimoni àti Tabori, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.
[78] Láti ẹ̀yà Reubeni rékọjá Jordani ìlà-oòrùn Jeriko wọ́n gba Beseri nínú aginjù Jahisa,
[79] Kedemoti àti Mefaati, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.
[80] Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Gadi wọ́n gba Ramoti ní Gileadi Mahanaimu,
[81] Heṣboni àti Jaseri lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.