Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 3:11

[1] Ní àkókò kan, Dafidi kọlu àwọn ará Filistini, ó sì ṣẹ́gun wọn. Ó sì mú Gati àti àwọn ìletò agbègbè rẹ̀ kúrò lábẹ́ ìdarí àwọn ará Filistini.

[2] Dafidi borí àwọn ará Moabu, wọ́n sì di ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì mú owó òde wá.

[3] Síbẹ̀, Dafidi sì kọlu Hadadeseri ọba Soba ní Hamati, bí ó ti ń lọ láti fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ létí odò Eufurate.

[4] Dafidi fi agbára gba ẹgbẹ̀rún (1,000) kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) agun-kẹ̀kẹ́ àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) ológun ilẹ̀. Ó sì já gbogbo ọgọ́rùn-ún iṣan ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin náà.

[5] Nígbà ti àwọn ará Siria ti Damasku wá láti ran Hadadeseri ọba Soba lọ́wọ́, Dafidi lu ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) wọn bọ lẹ̀.

[6] Ó sì fi àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ sínú ìjọba Siria ti Damasku, àwọn ará Siria sì ń sìn ní abẹ́ rẹ̀, wọ́n sì mú owó ìṣákọ́lẹ̀ wá. Olúwa sì ń fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní ibi gbogbo tí ó bá lọ.

[7] Dafidi mú àpáta wúrà tí àwọn ìjòyè Hadadeseri gbé, ó sì gbé wọn wá sí Jerusalẹmu.

[8] Láti Tibhati àti Kuni, àwọn ìlú Hadadeseri, Dafidi kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ idẹ tí Solomoni lò láti fi ṣe okùn idẹ, àwọn òpó àti oríṣìí ohun èlò idẹ.

[9] Nígbà tí Tou ọba Hamati gbọ́ pé Dafidi ti borí gbogbo ọmọ-ogun Hadadeseri ọba Soba.

[10] Ó rán ọmọ rẹ̀ Hadoramu sí ọba Dafidi láti kí i àti láti lọ bá a yọ̀ lórí ìṣẹ́gun rẹ̀ nínú ogun lórí Hadadeseri, tí ó wà lójú ogun pẹ̀lú Tou. Hadoramu mú oríṣìíríṣìí ohun èlò ti wúrà àti fàdákà àti idẹ wá.

[11] Ọba Dafidi ya ohun èlò wọ́n yí sí mímọ́ fún Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe pẹ̀lú fàdákà àti wúrà tí ó ti mú láti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí: Edomu àti Moabu, ará Ammoni àti àwọn ará Filistini àti Amaleki.

[12] Abiṣai ọmọ Seruiah lu ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) ará Edomu bolẹ̀ ní àfonífojì Iyọ̀.

[13] Ó fi ẹgbẹ́ ogun sí Edomu, gbogbo àwọn ará Edomu sì ń sìn ní abẹ́ Dafidi. Olúwa fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibí tí ó bá lọ.

[14] Dafidi jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli, ó sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀.

[15] Joabu ọmọ Seruiah jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun; Jehoṣafati ọmọ Ahiludi jẹ́ akọ̀wé ìrántí;

[16] Sadoku ọmọ Ahitubu àti Abimeleki ọmọ Abiatari jẹ́ àwọn àlùfáà; Ṣafṣa jẹ́ akọ̀wé;

[17] Benaiah ọmọ Jehoiada jẹ́ olórí àwọn Kereti àti Peleti; àwọn ọmọ Dafidi sì ni àwọn olóyè oníṣẹ́ ní ọ̀dọ̀ ọba.

Ìwé Kronika Kìn-ín-ní — Chapters