[1] Satani sì dúró ti Israẹli, ó sì ti Dafidi láti ka iye Israẹli.
[2] Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì wí fún Joabu àti àwọn olórí àwọn ènìyàn pé, “Lọ kí o ka iye àwọn ọmọ Israẹli láti Beerṣeba títí dé Dani. Kí o sì padà mú iye wọn fún mi wa, kí èmi kí ó le mọ iye tí wọ́n jẹ́.”
[3] Ṣùgbọ́n Joabu dá a lóhùn pé, “Kí Olúwa kí ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ pọ̀ sí ní ìgbà ọgọ́rùn-ún ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ọba olúwa mi, gbogbo wọn kì í ha ṣe ìránṣẹ́ olúwa ni? Kí ni ó dé tí olúwa mi ṣe fẹ́ ṣè yìí? Kí ni ó de tí yóò fi mú ẹ̀bi wá sórí Israẹli?”
[4] Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ọba borí tí Joabu. Bẹ́ẹ̀ ni Joabu jáde lọ, ó sì la gbogbo Israẹli já, ó sí dé Jerusalẹmu.
[5] Joabu sì fi àpapọ̀ iye àwọn ènìyàn náà fún Dafidi. Ní gbogbo Israẹli, ó sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún àti ọ̀kẹ́ márùn-ún ènìyàn (1,100,000) tí ń kọ́ idà, Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́tàlélógún lé ẹgbàárùn-ún (470,000) ọkùnrin tí ń kọ́ idà.
[6] Ṣùgbọ́n Joabu kó àwọn Lefi àti Benjamini mọ́ iye wọn, nítorí àṣẹ ọba jẹ́ ìríra fún un.
[7] Àṣẹ yìí pẹ̀lú sì jẹ́ búburú lójú Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ó sì díyàjẹ Israẹli.
[8] Nígbà náà Dafidi sọ fún Ọlọ́run pé, èmi ti dẹ́ṣẹ̀ gidigidi nípa ṣíṣe èyí. Nísinsin yìí, èmi bẹ̀ ọ́, mú ìjẹ̀bi àwọn ìránṣẹ́ rẹ kúrò. Èmi ti hùwà aṣiwèrè gidigidi.
[9] Olúwa sì fi fún Gadi, aríran Dafidi pé.
[10] “Lọ kí o sì wí fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, èmi fi nǹkan mẹ́ta lọ̀ ọ́; yan ọ̀kan nínú wọn, kí èmi ó sì ṣe é sí ọ.’ ”
[11] Bẹ́ẹ̀ ni Gadi tọ Dafidi wá, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Yan fún ara rẹ.
[12] Ọdún mẹ́ta ìyàn, tàbí ìparun ní oṣù mẹ́ta níwájú àwọn ọ̀tá rẹ, pẹ̀lú idà wọn láti lé ọ bá, tàbí ọjọ́ mẹ́ta idà Olúwa ọjọ́ àjàkálẹ̀-ààrùn ní ilẹ̀ náà, pẹ̀lú àwọn angẹli Olúwa láti pa gbogbo agbègbè Israẹli run.’ Nísinsin yìí ǹjẹ́, rò ó wò, èsì wo ni èmi yóò mú padà tọ ẹni tí ó rán mi.”
[13] Dafidi sì wí fún Gadi pé, “Ìyọnu ńlá bá mi. Jẹ́ kí èmi kí ó ṣubú sí ọwọ́ Olúwa nísinsin yìí, nítorí tí àánú rẹ̀ pọ̀ gidigidi, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí èmi kí o ṣubú sí ọwọ́ àwọn ènìyàn.”
[14] Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa rán àjàkálẹ̀-ààrùn lórí Israẹli, àwọn tí ó ṣubú ní Israẹli jẹ́ ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) ènìyàn.
[15] Ọlọ́run sì rán angẹli kan sí Jerusalẹmu láti pa wọ́n run. Ṣùgbọ́n bí angẹli ti ń pa wọ́n run, Olúwa sì wò. Ó sì káàánú nítorí ibi náà, ó sì wí fún angẹli tí ó pa àwọn ènìyàn náà run pé, “Ó ti tó! Dá ọwọ́ rẹ dúró.” Angẹli Olúwa náà sì dúró níbi ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi.
[16] Dafidi sì wòkè ó sì rí angẹli Olúwa dúró láàrín ọ̀run àti ayé pẹ̀lú idà fífàyọ ní ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì nà án sórí Jerusalẹmu. Nígbà náà Dafidi àti àwọn àgbàgbà, sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da ojú wọn bolẹ̀.
[17] Dafidi sì wí fún Ọlọ́run pé, “Èmi ha kọ́ ni mo pàṣẹ àti ka àwọn jagunjagun ènìyàn? Èmi ni ẹni náà tí ó dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun búburú pàápàá, ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti àgùntàn wọ̀nyí, kí ni wọ́n ṣe? Èmí bẹ̀ ọ́ Olúwa Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára mi àti àwọn ìdílé baba mi, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí àjàkálẹ̀-ààrùn yìí kí ó dúró lórí àwọn ènìyàn rẹ.”
[18] Nígbà náà angẹli Olúwa náà pàṣẹ fún Gadi láti sọ fún Dafidi pé, kí Dafidi kí ó gòkè lọ, kí ó sì tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa lórí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi.
[19] Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì gòkè lọ pẹ̀lú ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ tí Gadi ti sọ ní orúkọ Olúwa.
[20] Nígbà tí Arauna sì ń pakà lọ́wọ́, ó sì yípadà ó sì rí angẹli; àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa ará wọn mọ́.
[21] Bí Dafidi sì ti dé ọ̀dọ̀ Arauna, Arauna sì wò, ó sì rí Dafidi, ó sì ti ibi ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ jáde, ó sì wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú Dafidi.
[22] Dafidi sì wí fún Arauna pé, “Jẹ́ kí èmi kí ó ni ibi ìpakà rẹ kí èmi kí ó sì lè tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa, ìwọ ó sì fi fún mi ni iye owó rẹ̀ pípé, kí a lè dá àjàkálẹ̀-ààrùn dúró lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn.”
[23] Arauna sì wí fún Dafidi pé, “Mú un fún ara rẹ, sì jẹ́ kí olúwa mi ọba kí ó ṣe ohun tí ó dára lójú rẹ̀. Wò ó, èmí yóò fún ọ ní àwọn màlúù fún ẹbọ sísun, àti ohun èlò ìpakà fún igi, àti ọkà fún ọrẹ oúnjẹ. Èmi yóò fun ọ ní gbogbo èyí.”
[24] Ṣùgbọ́n ọba Dafidi dá Arauna lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n èmi yóò rà á ní iye owó rẹ̀ ní pípé, nítorí èmi kì yóò èyí tí ó jẹ́ tìrẹ fún Olúwa, tàbí láti rú ẹbọ sísun tí kò ná mi ní ohun kan.”
[25] Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi san ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì wúrà fún Arauna nípa ìwọ̀n fún ibẹ̀ náà.
[26] Dafidi sì tẹ́ pẹpẹ fún Olúwa níbẹ̀ ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ọpẹ́. Ó sì ké pe Olúwa, Olúwa sì fi iná dá a lóhùn láti òkè ọ̀run wá lórí pẹpẹ fún ẹbọ ọrẹ sísun.
[27] Nígbà náà Olúwa sọ̀rọ̀ sí angẹli, ó sì gbé idà padà bọ̀ sínú àkọ̀ rẹ̀.
[28] Ní àkókò náà nígbà tí Dafidi sì rí wí pé Olúwa ti dá a lóhùn lórí ilẹ̀ ìpakà ti Arauna ará Jebusi, ó sì rú ẹbọ sísun níbẹ̀.
[29] Àgọ́ Olúwa tí Mose ti ṣe ní aginjù, àti pẹpẹ ẹbọ sísun wà lórí ibi gíga ní Gibeoni ní àkókò náà.
[30] Ṣùgbọ́n Dafidi kò lè lọ síwájú rẹ̀ láti béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí tí ó bẹ̀rù nípa idà ọwọ́ angẹli Olúwa.