[1] “Ǹjẹ́ ìwọ le è fi ìwọ̀ fa Lefitani jáde? Tàbí ìwọ lè fi okùn so ahọ́n rẹ̀ mọ́lẹ̀?
[2] Ìwọ lè fi okùn bọ̀ ọ́ ní í mú, tàbí fi ìwọ̀ ẹ̀gún gun ní ẹ̀rẹ̀kẹ́?
[3] Òun ha jẹ́ bẹ ẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀ rẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí òun ha bá ọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́?
[4] Òun ha bá ọ dá májẹ̀mú bí? Ìwọ ó ha máa mú ṣe ẹrú láéláé bí?
[5] Ìwọ ha lè ba sáré bí ẹni pé ẹyẹ ni, tàbí ìwọ ó dè é fún àwọn ọmọbìnrin ìránṣẹ́ rẹ̀?
[6] Ẹgbẹ́ àwọn apẹja yóò ha máa tà á bí? Wọn ó ha pín láàrín àwọn oníṣòwò?
[7] Ìwọ ha lè fi ọ̀kọ̀-irin gun awọ rẹ̀, tàbí orí rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ìpẹja.
[8] Fi ọwọ́ rẹ lé e lára, ìwọ ó rántí ìjà náà, ìwọ kì yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
[9] Kíyèsi, ìgbìyànjú láti mú un ní asán; ní kìkì ìrí rẹ̀ ara kì yóò ha rọ̀ ọ́ wẹ̀sì?
[10] Kò sí ẹni aláyà lílé tí ó lè ru sókè. Ǹjẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú mi.
[11] Ta ni ó kọ́kọ́ ṣe fún mi, tí èmi ìbá fi san án fún un? Ohunkóhun ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run gbogbo, tèmi ni.
[12] “Èmi kì yóò fi ẹ̀yà ara Lefitani, tàbí ipá rẹ, tàbí ìhámọ́ra rẹ tí ó ní ẹwà pamọ́.
[13] Ta ni yóò lè rídìí aṣọ àpáta rẹ̀? Tàbí ta ni ó lè súnmọ́ ọ̀nà méjì eyín rẹ̀?
[14] Ta ni ó lè ṣí ìlẹ̀kùn iwájú rẹ̀? Àyíká ẹ̀yin rẹ ni ìbẹ̀rù ńlá.
[15] Ìpẹ́ lílé ní ìgbéraga rẹ̀; ó pàdé pọ̀ tímọ́tímọ́ bí àmì èdìdì.
[16] Èkínní fi ara mọ́ èkejì tó bẹ́ẹ̀ tí afẹ́fẹ́ kò lè wọ àárín wọn.
[17] Èkínní fi ara mọ́ èkejì rẹ̀; wọ́n lè wọ́n pọ̀ tí a kò lè mọ̀ wọ́n.
[18] Nípa sí sin rẹ̀ ìmọ́lẹ̀ á mọ́, ojú rẹ̀ a sì dàbí ìpéǹpéjú òwúrọ̀.
[19] Láti ẹnu rẹ ni ọ̀wọ́-iná ti jáde wá, ìpẹ́pẹ́ iná a sì ta jáde.
[20] Láti ihò imú rẹ ni èéfín ti jáde wá, bí ẹni pé láti inú ìkòkò tí a fẹ́ iná ìfèéfèé lábẹ́ rẹ̀.
[21] Èémí rẹ̀ tiná bọ ẹ̀yin iná, ọ̀wọ́-iná sì ti ẹnu rẹ̀ jáde.
[22] Ní ọrùn rẹ̀ ní agbára kù sí, àti ìbànújẹ́ àyà sì padà di ayọ̀ níwájú rẹ̀.
[23] Jabajaba ẹran rẹ̀ dìjọ pọ̀, wọ́n múra gírí fún ara wọn, a kò lè sí wọn ní ipò.
[24] Àyà rẹ̀ dúró gbagidi bí òkúta, àní, ó le bi ìyá ọlọ.
[25] Nígbà tí ó bá gbé ara rẹ̀ sókè, àwọn alágbára bẹ̀rù; nítorí ìbẹ̀rù ńlá, wọ́n dààmú.
[26] Ọ̀kọ̀ tàbí idà, tàbí ọfà, ẹni tí ó ṣá a kò lè rán an.
[27] Ó ká irin sí ibi koríko gbígbẹ àti idẹ si bi igi híhù.
[28] Ọfà kò lè mú un sá; òkúta kànnakánná lọ́dọ̀ rẹ̀ dàbí àgékù koríko.
[29] Ó ka ẹṣin sí bí àgékù ìdì koríko; ó rẹ́rìn-ín sí mímì ọ̀kọ̀.
[30] Òkúta mímú ń bẹ nísàlẹ̀ abẹ́ rẹ̀, ó sì tẹ́ ohun mímú ṣóńṣó sórí ẹrẹ̀.
[31] Ó mú ibú omi hó bí ìkòkò; ó sọ̀ agbami òkun dàbí kólòbó ìkunra.
[32] Ó mú ipa ọ̀nà tan lẹ́yìn rẹ̀; ènìyàn a máa ka ibú sí ewú arúgbó.
[33] Lórí ilẹ̀ ayé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀, tí a dá láìní ìbẹ̀rù.
[34] Ó bojú wo ohun gíga gbogbo, ó sì nìkan jásí ọba lórí gbogbo àwọn ọmọ ìgbéraga.”