Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 3:15

[1] “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, àwọn tí mo gbà ní àbúrò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà baba ẹni tí èmi kẹ́gàn láti tò pẹ̀lú àwọn ajá nínú agbo ẹran mi.

[2] Kí ni ìwúlò agbára ọwọ́ wọn sí mi, níwọ̀n ìgbà tí agbára wọn ti fi wọ́n sílẹ̀?

[3] Wọ́n rù nítorí àìní àti ìyàn wọ́n ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ gbígbẹ ní ibi ìkọ̀sílẹ̀ ní òru.

[4] Àwọn ẹni tí ń já ewé iyọ̀ ní ẹ̀bá igbó; gbogbo igikígi ni oúnjẹ jíjẹ wọn.

[5] A lé wọn kúrò láàrín ènìyàn, àwọn ènìyàn sì pariwo lé wọn lórí bí ẹní pariwo lé olè lórí.

[6] A mú wọn gbe inú pàlàpálá òkúta àfonífojì, nínú ihò ilẹ̀ àti ti òkúta.

[7] Wọ́n ń dún ní àárín igbó wọ́n kó ara wọn jọ pọ̀ ní abẹ́ ẹ̀gún neteli.

[8] Àwọn ọmọ ẹni tí òye kò yé, àní àwọn ọmọ lásán, a sì lé wọn jáde kúrò ní orí ilẹ̀.

[9] “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àwọn ọmọ wọn ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà nínú orin; àní èmi di ẹni ìṣọ̀rọ̀ sí láàrín wọn.

[10] Wọ́n kórìíra mi; wọ́n sá kúrò jìnnà sí mi, wọn kò sì bìkítà láti tutọ́ sí mi lójú.

[11] Nítorí Ọlọ́run ti tú okùn ìyè mi, ó sì pọ́n mi lójú; àwọn pẹ̀lú sì dẹ ìdẹ̀kùn níwájú mi.

[12] Àwọn ènìyàn lásán dìde ní apá ọ̀tún mi; wọ́n tì ẹsẹ̀ mi kúrò, wọ́n sì la ipa ọ̀nà ìparun sílẹ̀ dè mí.

[13] Wọ́n da ipa ọ̀nà mi rú; wọ́n sì sọ ìparun mi di púpọ̀, àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.

[14] Wọ́n ya sí mi bí i omi tí ó ya gbuuru; ní ariwo ńlá ni wọ́n rọ́ wá.

[15] Ẹ̀rù ńlá bà mí; wọ́n lépa ọkàn mi bí ẹ̀fúùfù, àlàáfíà mi sì kọjá lọ bí àwọ̀ sánmọ̀.

[16] “Àti nísinsin yìí, ayé mi n yòrò lọ díẹ̀díẹ̀; ọjọ́ ìpọ́njú mi dì mímú.

[17] Òru gún mi nínú egungun mi, èyí tí ó bù mí jẹ kò sì sinmi.

[18] Nípa agbára ńlá rẹ̀ Ọlọ́run wà bí aṣọ ìbora fún mi, ó sì lẹ̀ mọ́ mi ní ara yíká bí aṣọ ìlekè mi.

[19] Ọlọ́run ti mú mi lọ sínú ẹrẹ̀, èmi sì dàbí eruku àti eérú.

[20] “Èmi ké pè ọ́ ìwọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi lóhùn; èmi dìde dúró ìwọ sì wò mí lásán.

[21] Ìwọ padà di ẹni ìkà sí mi; ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ fi dè mí ní ọ̀nà.

[22] Ìwọ gbé mi sókè sí inú ẹ̀fúùfù, ìwọ mú mi fò lọ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì sọ mí di asán pátápátá.

[23] Èmi sá à mọ̀ pé ìwọ yóò mú mi lọ sínú ikú, sí ilé ìpéjọ tí a yàn fún gbogbo alààyè.

[24] “Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnìkan kí yóò ha nawọ́ rẹ̀ nígbà ìṣubú rẹ̀, tàbí kì yóò ké nínú ìparun rẹ̀.

[25] Èmi kò ha sọkún bí fún ẹni tí ó wà nínú ìṣòro? Ọkàn mi kò ha bàjẹ́ fún tálákà bí?

[26] Nígbà tí mo fojú ṣọ́nà fún àlàáfíà, ibi sì dé; nígbà tí mo dúró de ìmọ́lẹ̀, òkùnkùn sì dé.

[27] Ikùn mí n ru kò sì sinmi, ọjọ́ ìpọ́njú ti dé bá mi.

[28] Èmí ń rìn kiri nínú ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú oòrùn; èmi dìde dúró ní àwùjọ mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́.

[29] Èmi ti di arákùnrin ìkookò, èmi di ẹgbẹ́ àwọn ògòǹgò.

[30] Àwọ̀ mi di dúdú ní ara mi; egungun mi sì jórun fún ooru.

[31] Ohun èlò orin mi pẹ̀lú sì di ti ọ̀fọ̀, àti ìpè orin mi sì di ohùn àwọn tí ń sọkún.

Ìwé Jobu — Chapters