[1] Ìgbà náà ní Sofari, ará Naama dáhùn, ó sì wí pé,
[2] “Nítorí náà ní ìrò inú mi dá mi lóhùn, àti nítorí èyí náà ní mo sì yára si gidigidi.
[3] Mo ti gbọ́ ẹ̀san ẹ̀gàn mi, ẹ̀mí òye mi sì dá mi lóhùn.
[4] “Ìwọ kò mọ̀ èyí rí ní ìgbà àtijọ́, láti ìgbà tí a sọ ènìyàn lọ́jọ̀ sílé ayé,
[5] pé, orin ayọ̀ ènìyàn búburú, ìgbà kúkúrú ni, àti pé, ní ìṣẹ́jú kan ní ayọ̀ àgàbàgebè?
[6] Bí ọláńlá rẹ̀ tilẹ̀ gòkè dé ọ̀run, ti orí rẹ̀ sì kan àwọsánmọ̀;
[7] ṣùgbọ́n yóò ṣègbé láéláé bí ìgbẹ́ ara rẹ̀; àwọn tí ó ti rí i rí yóò wí pé, ‘Òun ha dà?’
[8] Yóò fò lọ bí àlá, a kì yóò sì rí i, àní a ó lé e lọ bi ìran òru.
[9] Ojú tí ó ti rí i rí kì yóò sì rí i mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kì yóò sì ri i mọ́.
[10] Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wá àti rí ojúrere lọ́dọ̀ tálákà, ọwọ́ rẹ̀ yóò sì kó ọrọ̀ wọn padà.
[11] Egungun rẹ̀ kún fún agbára ìgbà èwe rẹ̀, tí yóò bá a dùbúlẹ̀ nínú erùpẹ̀.
[12] “Bí ìwà búburú tilẹ̀ dún ní ẹnu rẹ̀, bí ó tilẹ̀ pa á mọ́ nísàlẹ̀ ahọ́n rẹ̀,
[13] bí ó tilẹ̀ dá a sì, tí kò si kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí ó pa á mọ́ síbẹ̀ ní ẹnu rẹ̀,
[14] ṣùgbọ́n oúnjẹ rẹ̀ nínú ikùn rẹ̀ ti yípadà, ó jásí òróró paramọ́lẹ̀ nínú rẹ̀;
[15] Ó ti gbé ọrọ̀ mì, yóò sì tún bí i jáde; Ọlọ́run yóò pọ̀ ọ́ yọ jáde láti inú rẹ̀ wá.
[16] Ó ti fà oró paramọ́lẹ̀ mú; ahọ́n ejò olóró ní yóò pa á.
[17] Kì yóò rí odò wọ̀n-ọn-nì, ìṣàn omi, odò tí ń ṣàn fún oyin àti ti òrí-àmọ́.
[18] Ohun tí ó ṣiṣẹ́ fún ni yóò mú un padà, kí yóò sì gbé e mì; gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ tí ó ní, kì yóò sì ìgbádùn nínú rẹ̀.
[19] Nítorí tí ó fi owó rẹ̀ ni tálákà lára, ó sì ti pẹ̀yìndà si wọ́n; nítorí ti ó fi agbára gbé ilé tí òun kò kọ́.
[20] “Nítorí òun kò mọ̀ ìwà pẹ̀lẹ́ nínú ara rẹ̀, kì yóò sì gbà nínú èyí tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ sílẹ̀.
[21] Ohun kan kò kù fún jíjẹ́ rẹ̀; nítorí náà ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì yóò dúró pẹ́.
[22] Nínú ànító rẹ̀, ìdààmú yóò dé bá a; àwọn ènìyàn búburú yóò dáwọ́jọ lé e lórí.
[23] Yóò sì ṣe, nígbà tí ó bá fẹ́ jẹun, Ọlọ́run yóò fà ríru ìbínú rẹ̀ sí í lórí, nígbà tó bá ń jẹun lọ́wọ́, yóò sì rọ òjò ìbínú rẹ̀ lé e lórí.
[24] Bi o tilẹ̀ sá kúrò lọ́wọ́ ohun ìjà ìrìn; ọrun akọ irin ní yóò ta a po yọ.
[25] O fà á yọ, ó sì jáde kúrò lára; idà dídán ní ń jáde láti inú òróòro wá. Ẹ̀rù ńlá ń bẹ ní ara rẹ̀;
[26] òkùnkùn biribiri ní a ti pamọ́ fún ìṣúra rẹ̀. Iná ti a kò fẹ́ ní yóò jó o run yóò sì jẹ èyí tí ó kù nínú àgọ́ rẹ̀ run.
[27] Ọ̀run yóò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn, ayé yóò sì dìde dúró sí i.
[28] Ìbísí ilé rẹ̀ yóò kọjá lọ, àti ohun ìní rẹ̀ yóò sàn dànù lọ ni ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run.
[29] Èyí ni ìpín ènìyàn búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, àti ogún tí a yàn sílẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”