Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 2:52

[1] “Wò ó, ojú mi ti rí gbogbo èyí rí, etí mí sì gbọ́, ó sì ti yé mi.

[2] Ohun tí ẹ̀yin mọ̀, èmi mọ̀ pẹ̀lú, èmi kò kéré sí i yin.

[3] Nítòótọ́ èmi ó bá Olódùmarè sọ̀rọ̀, èmi sì ń fẹ́ bá Ọlọ́run sọ àsọyé.

[4] Ẹ̀yin fi irọ́ bá mi sọ̀rọ̀, oníṣègùn lásán ni gbogbo yín.

[5] Háà! ẹ̀yin kì bá kúkú dákẹ́! Èyí ni kì bá sì ṣe ọgbọ́n yín.

[6] Ẹ gbọ́ àwíyé mi nísinsin yìí; ẹ sì fetísílẹ̀ sí àròyé ẹnu mi.

[7] Ẹ̀yin fẹ́ sọ ìsọkúsọ fún Ọlọ́run? Ki ẹ sì fi ẹ̀tàn sọ̀rọ̀ gbè é?

[8] Ẹ̀yin fẹ́ ṣe ojúsàájú rẹ̀? Ẹ̀yin fẹ́ gbèjà fún Ọlọ́run?

[9] Ó ha dára to tí yóò hú àṣírí yín síta, tàbí kí ẹ̀yin tàn án bí ẹnìkan ti í tan ẹnìkejì?

[10] Yóò máa bá yín wí nítòótọ́, bí ẹ̀yin bá ṣe ojúsàájú ènìyàn níkọ̀kọ̀.

[11] Ìwà ọlá rẹ̀ kì yóò bà yín lẹ́rù bí? Ìpayà rẹ̀ kì yóò pá yín láyà?

[12] Àwọn òwe yín dàbí eérú, bẹ́ẹ̀ ni àwọn odi ìlú yin dàbí amọ̀.

[13] “Ẹ pa ẹnu yín mọ́ kúrò lára mi, kí èmi kí ó lè sọ̀rọ̀, ki ohun tí ń bọ̀ wá í bá mi, le è máa bọ̀.

[14] Ǹjẹ́ nítorí kí ni èmi ṣe ń fi eyín mi bu ẹran-ara mi jẹ, tí mo sì gbé ẹ̀mí mi lé ara mi lọ́wọ́?

[15] Bí ó tilẹ̀ pa mí, síbẹ̀ èmi ó máa gbẹ́kẹ̀lé e, èmi ó máa tẹnumọ́ ọ̀nà mi níwájú rẹ̀.

[16] Èyí ni yóò sì ṣe ìgbàlà mi, àgàbàgebè kì yóò wá síwájú rẹ̀.

[17] Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi ní ìfarabalẹ̀, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mí dún ni etí yín.

[18] Wò ó nísinsin yìí, èmi ti mura ọ̀ràn mi sílẹ̀; èmi mọ̀ pé a ó dá mi láre.

[19] Ta ni òun ti yóò bá mi ṣàròyé? Ǹjẹ́ nísinsin yìí, èmi fẹ́ pa ẹnu mi mọ́, èmi ó sì jọ̀wọ́ ẹ̀mí mi lọ́wọ́.

[20] “Ṣùgbọ́n, má ṣe ṣe ohun méjì yìí sí mi, nígbà náà ni èmi kì yóò sì fi ara mi pamọ́ kúrò fún ọ.

[21] Fa ọwọ́ rẹ sẹ́yìn kúrò lára mi, má sì jẹ́ kí ẹ̀rù rẹ kí ó pá mi láyà.

[22] Nígbà náà ni kí ìwọ kí ó pè, èmi o sì dáhùn, tàbí jẹ́ kí ń máa sọ̀rọ̀, ki ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.

[23] Mélòó ní àìṣedéédéé àti ẹ̀ṣẹ̀ mi? Mú mi mọ̀ ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ mi.

[24] Nítorí kí ni ìwọ ṣe pa ojú rẹ mọ́, tí o sì yàn mí ní ọ̀tá rẹ?

[25] Ìwọ ó fa ewé ti afẹ́fẹ́ ń fẹ́ síyìn-ín sọ́hùn-ún ya bi? Ìwọ a sì máa lépa ìyàngbò?

[26] Nítorí pé ìwọ kọ̀wé ohun kíkorò sí mi, o sì mú mi jogún àìṣedéédéé èwe mi.

[27] Ìwọ kàn àbà mọ́ mi lẹ́sẹ̀ pẹ̀lú, ìwọ sì ń wò ipa ọ̀nà ìrìn mi ní àwòfín; nípa fífi ìlà yí gígísẹ̀ mi ká.

[28] “Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn ń ṣègbé bí ohun ìdíbàjẹ́, bi aṣọ tí kòkòrò jẹ.

Ìwé Jobu — Chapters