Listen to this chapter • 0:39
[1] Nígbà náà ní Bilidadi, ará Ṣuhi, dáhùn wí pé,
[2] “Ìjọba àti ẹ̀rù ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀, òun ní i ṣe ìlàjà ní ibi gíga gíga ọ̀run.
[3] Àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ní ìyè bí, tàbí ara ta ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí?
[4] Èéha ti ṣe tí a ó fi dá ènìyàn láre lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Tàbí ẹni tí a bí láti inú obìnrin wá yóò ha ṣe mọ́?
[5] Kíyèsi i, òṣùpá kò sì lè tàn ìmọ́lẹ̀, àní àwọn ìràwọ̀ kò mọ́lẹ̀ ní ojú rẹ̀,
[6] kí a má sọ ènìyàn tí i ṣe ìdin, àti ọmọ ènìyàn tí í ṣe kòkòrò!”