[1] Jobu wá dáhùn, ó sì wí pé,
[2] “Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ dáradára sì àwọn ọ̀rọ̀ mi, kí èyí kí ó jásí ìtùnú fún mi.
[3] Ẹ jọ̀wọ́ mi ki èmi sọ̀rọ̀; lẹ́yìn ìgbà ìwọ le máa fi mi ṣẹ̀sín ń ṣo.
[4] “Àròyé mi ha ṣe sí ènìyàn bí? Èétise tí ọkàn mi kì yóò fi ṣe àìbalẹ̀?
[5] Ẹ wò mí fín, kí ẹnu kí ó sì yà yín, kí ẹ sì fi ọwọ́ lé ẹnu yín.
[6] Àní nígbà tí mo rántí, ẹ̀rù bà mí, ìwárìrì sì mú mi lára.
[7] Nítorí kí ní ènìyàn búburú fi wà ní ayé, tí wọ́n gbó, àní tí wọ́n di alágbára ní ipa?
[8] Irú-ọmọ wọn fi ìdí kalẹ̀ ní ojú wọn pẹ̀lú wọn, àti ọmọ ọmọ wọn ní ojú wọn.
[9] Ilé wọn wà láìní ewu àti ẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá ìbínú Ọlọ́run kò sí lára wọn.
[10] Akọ màlúù wọn a máa gùn, kì í sì tàsé; abo màlúù wọn a máa bí, kì í sì í ṣẹ́yun.
[11] Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọn wẹ́wẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jo kiri.
[12] Wọ́n mú ohun ọ̀nà orin, ìlù àti haapu; wọ́n sì ń yọ̀ sí ohùn fèrè.
[13] Wọ́n n lo ọjọ́ wọn nínú ọrọ̀; wọn sì lọ sí ipò òkú ní àlàáfíà.
[14] Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa!’ Nítorí pé wọn kò fẹ́ ìmọ̀ ipa ọ̀nà rẹ.
[15] Kí ni Olódùmarè tí àwa ó fi máa sìn in? Èrè kí ni a ó sì jẹ bí àwa ba gbàdúrà sí i?
[16] Kíyèsi i, àlàáfíà wọn kò sí nípa ọwọ́ wọn; ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi réré.
[17] “Ìgbà mélòó mélòó ní a ń pa fìtílà ènìyàn búburú kú? Ìgbà mélòó mélòó ní ìparun wọn dé bá wọn, tí Ọlọ́run sì í máa pín ìbìnújẹ́ nínú ìbínú rẹ̀?
[18] Wọ́n dàbí àgékù koríko níwájú afẹ́fẹ́, àti bí ìyàngbò, tí ẹ̀fúùfù ńlá fẹ́ lọ.
[19] Ẹ̀yin wí pé, ‘Ọlọ́run to ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jọ fún àwọn ọmọ rẹ̀.’ Jẹ́ kí ó san án fún un, yóò sì mọ̀ ọ́n.
[20] Ojú rẹ̀ yóò rí ìparun ara rẹ̀, yóò sì máa mu nínú ríru ìbínú Olódùmarè.
[21] Nítorí pé àlàáfíà kí ni ó ní nínú ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, nígbà tí a bá ké iye oṣù rẹ̀ kúrò ní agbede-méjì?
[22] “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni le kọ Ọlọ́run ní ìmọ̀? Òun ní í sá à ń ṣe ìdájọ́ ẹni ibi gíga.
[23] Ẹnìkan a kú nínú pípé agbára rẹ̀, ó wà nínú ìrora àti ìdákẹ́ pátápátá.
[24] Ọpọ́n rẹ̀ kún fún omi ọmú, egungun rẹ̀ sì tutù fún ọ̀rá.
[25] Ẹlòmíràn a sì kú nínú kíkorò ọkàn rẹ̀, tí kò sì fi inú dídùn jẹun.
[26] Wọ́n o dùbúlẹ̀ bákan náà nínú erùpẹ̀, kòkòrò yóò sì ṣùbò wọ́n.
[27] “Kíyèsi i, èmi mọ̀ èrò inú yín àti àrékérekè ọkàn yín láti ṣe ìlòdì sí mi.
[28] Nítorí tí ẹ̀yin wí pé, ‘Níbo ní ilé ọmọ-aládé, àti níbo ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú nì gbé wà?’
[29] Ẹ̀yin kò béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ń kọjá lọ ní ọ̀nà? Ẹ̀yin kò mọ̀ àmì wọn,
[30] pé ènìyàn búburú ní a fi pamọ́ fún ọjọ́ ìparun. A ó sì mú wọn jáde ní ọjọ́ ríru ìbínú.
[31] Ta ni yóò tako ipa ọ̀nà rẹ̀ lójúkojú, ta ni yóò sì san án padà fún un ní èyí tí ó ti ṣe?
[32] Síbẹ̀ a ó sì sin ín ní ọ̀nà ipò òkú, a ó sì máa ṣọ́ ibojì òkú.
[33] Ògúlùtu àfonífojì yóò dùn mọ́ ọn. Gbogbo ènìyàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, bí ènìyàn àìníye ti lọ síwájú rẹ̀.
[34] “Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin fi ń tù mí nínú lásán, bí ò ṣe pé ní ìdáhùn yín, àrékérekè wa níbẹ̀!”