[1] “Ìránṣẹ́ mi nìyìí, ẹni tí mo gbéró, àyànfẹ́ mi nínú ẹni tí mo láyọ̀; Èmi yóò fi Ẹ̀mí mi sínú rẹ̀ òun yóò sì mú ìdájọ́ wá sórí àwọn orílẹ̀-èdè.
[2] Òun kì yóò pariwo tàbí kígbe sókè, tàbí kí ó gbóhùn rẹ̀ sókè ní òpópónà.
[3] Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́, àti òwú-fìtílà tí ń jó tan an lọ lòun kì yóò fẹ́ pa. Ní òdodo ni yóò mú ìdájọ́ wá;
[4] òun kì yóò kọsẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní rẹ̀wẹ̀sì títí tí yóò fi fi ìdájọ́ múlẹ̀ ní ayé. Nínú òfin rẹ̀ ni àwọn erékùṣù yóò fi ìrètí wọn sí.”
[5] Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí Ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run tí ó sì tẹ́ wọ́n sóde, tí ó tẹ́ ilẹ̀ ayé àti ohun gbogbo tí ó jáde nínú wọn, Ẹni tí ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní èémí àti ẹ̀mí fún gbogbo àwọn tí ń rìn nínú rẹ̀:
[6] “Èmi, Olúwa, ti pè ọ́ ní òdodo, Èmi yóò di ọwọ́ rẹ mú. Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn àti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà
[7] láti la àwọn ojú tí ó fọ́, láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbú àti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n àwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn.
[8] “Èmi ni Olúwa; orúkọ mi nìyìí! Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn tàbí ìyìn mi fún ère òrìṣà.
[9] Kíyèsi i, àwọn nǹkan àtijọ́ ti wáyé, àti àwọn nǹkan tuntun ni mo ti wí pé; kí wọn tó hù jáde mo ti kéde rẹ̀ fún ọ.”
[10] Kọ orin tuntun sí Olúwa ìyìn rẹ̀ láti òpin ilẹ̀ ayé wá, ẹ̀yin tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú Òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, ẹ̀yin erékùṣù, àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú wọn.
[11] Jẹ́ kí aginjù àti àwọn ìlú rẹ̀ kí ó gbé ohùn wọn sókè; jẹ́ kí ibùdó ti àwọn ìlú Kedari ń gbé máa yọ̀. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Sela kọrin fún ayọ̀; jẹ́ kí wọn pariwo láti orí òkè.
[12] Jẹ́ kí wọn fi ògo fún Olúwa àti kí wọn sì kéde ìyìn rẹ̀ ní erékùṣù.
[13] Olúwa yóò rìn jáde gẹ́gẹ́ bí i ọkùnrin alágbára, yóò ru owú sókè bí ológun; yóò kígbe nítòótọ́, òun yóò ké igbe ogun, òun yóò sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀.
[14] “Fún ìgbà pípẹ́ ni mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́, mo ti wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, mo sì kó ara ró. Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí, mo sọkún, mo sì ń mí hẹlẹ hẹlẹ.
[15] Èmi yóò sọ òkè ńlá àti kékeré di ahoro tí n ó sì gbẹ gbogbo ewéko rẹ̀ dànù, Èmi yóò sọ àwọn odò di erékùṣù n ó sì gbẹ àwọn adágún.
[16] Èmi yóò tọ àwọn afọ́jú ní ọ̀nà tí wọn kò tí ì mọ̀, ní ipa ọ̀nà tí ó ṣàjèjì sí wọn ni èmi yóò tọ́ wọn lọ; Èmi yóò sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájú wọn àti ibi pálapàla ni èmi ó sọ di kíkúnná. Àwọn nǹkan tí máa ṣe nìyìí; Èmi kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
[17] Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé òrìṣà, tí wọ́n wí fún ère pé, ‘Ẹ̀yin ni Ọlọ́run wa,’ ni a ó dá padà pẹ̀lú ìtìjú.
[18] “Gbọ́, ìwọ adití, wò ó, ìwọ afọ́jú, o sì rí!
[19] Ta ló fọ́jú bí kò ṣe ìránṣẹ́ mi, àti odi gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí mo rán? Ta ni ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a fi jìnmí, ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Olúwa?
[20] Ẹ̀yin ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan, ṣùgbọ́n ẹ kò ṣe àkíyèsí; etí yín yà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́ nǹkan kan.”
[21] Ó dùn mọ́ Olúwa nítorí òdodo rẹ̀ láti mú òfin rẹ lágbára àti ògo.
[22] Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan nìyìí tí a jà lógun tí a sì kó lẹ́rú, gbogbo wọn ni ó wà nínú ọ̀gbun, tàbí tí a fi pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n. Wọ́n ti di ìkógun, láìsí ẹnìkan tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀; wọ́n ti di ìkógun, láìsí ẹni tí yóò sọ pé, “Dá wọn padà.”
[23] Ta ni nínú yín tí yóò tẹ́tí sí èyí tàbí kí ó ṣe àkíyèsí gidi ní àsìkò tí ó ń bọ̀?
[24] Ta ni ó fi Jakọbu lélẹ̀ fún ìkógun, àti Israẹli sílẹ̀ fún onísùnmọ̀mí? Kì í ha ṣe Olúwa ni, ẹni tí àwa ti ṣẹ̀ sí? Nítorí pé wọn kò ní tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀; wọn kò mú òfin rẹ̀ ṣẹ.
[25] Nítorí náà ni ó ṣe rọ̀jò ìbínú un rẹ̀ lé wọn lórí, rògbòdìyàn ogun. Èyí tí ó fi ahọ́n iná yí wọn po, síbẹ̀ èdè kò yé wọn; ó jó wọn run, síbẹ̀ wọn kò fi sọ́kàn wọn rárá.